Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 12:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Àwọn arákùnrin rẹ àti àwọnìdílé—ti dà ọ́, kódà wọ́n ti kẹ̀yìn sí ọWọ́n ti hó lé ọ lórí;Má ṣe gbà wọ́n gbọ́bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ dáadáa.

7. Èmi yóò kọ ilé mi sílẹ̀,màá fi ìní mi sílẹ̀.Èmi yóò fi ẹni tí mo fẹ́lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.

8. Ìní mi ti dàbíkìnnìún nínú igbó sí miÓ ń bú ramúramù mọ́ mi;nítorí náà mo kórìíra rẹ̀.

9. Ìní kò ha ti dàbíẹyẹ kanna-kánnátí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ dòyì kọ tí wọ́n sì kọjú ìjà sí i?Lọ kí o lọ ṣe àkójọ gbogbo àwọn ẹranko búburú,kó wọn wá láti wá parun.

10. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣọ́ àgùntàn ni yóò sì ba oko àjàrà mi jẹ́,tí wọn yóò sì tẹ oko mi mọ́lẹ̀;Wọ́n ó sọ oko dídára mi diibi tí a ń da ìdọ̀tí sí.

11. A ó sọ ọ́ di aṣálẹ̀ ilẹ̀tí kò wúlò níwájú mi,gbogbo ilẹ̀ ni yóò di ahoronítorí kò sí ẹnìkankan tí yóò náání.

Ka pipe ipin Jeremáyà 12