Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 12:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa, olódodo ni ọ́ nígbàkúgbà,nígbà tí mo mú ẹjọ́ kan tọ̀ ọ́ wá.Síbẹ̀ èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀ nípa òdodo rẹ.Èéṣe tí ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú fi ń ṣe déédéé?Èéṣe tí gbogbo àwọn aláìsòdodo sì ń gbé ní ìrọ̀rùn?

2. Ó ti gbìn wọ́n, wọ́n sì ti fi egbò múlẹ̀,wọ́n dàgbà wọ́n sì so èso.Gbogbo ìgbà ni ó wà ní ètè wọn,o jìnnà sí ọkàn wọn.

3. Síbẹ̀ o mọ̀ mí ní Olúwa,o ti rí mi o sì ti dán èrò mi nípa rẹ wò.Wò ó, wọ́n lọ bí àgùntàn tí a fẹ́ pa.Yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ọjọ́ pípa.

4. Yóò ti pẹ́ tó tí ọ̀gbẹlẹ̀ yóò fi wà,tí gbogbo ewéko ìgbẹ́ sì ń rọ?Nítorí àwọn ènìyàn búburú ni ó ń gbé ibẹ̀.Àwọn ẹranko àti àwọn ẹyẹ ti ṣègbé,pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ènìyàn ń sọ pé,“Kò lè rí ohun tó ṣẹlẹ̀ síwa.”

5. Bí ìwọ bá ń bá ẹlẹ́sẹ̀ díje,tí àárẹ̀ sì mú ọ,báwo ni ìwọ yóò ṣe bá ẹṣin díje?Bí ìwọ bá kọsẹ̀ ní ilẹ̀ àlàáfíà,báwo ni ìwọ ó ṣe ṣe nínú ihà Jọ́dánì?

6. Àwọn arákùnrin rẹ àti àwọnìdílé—ti dà ọ́, kódà wọ́n ti kẹ̀yìn sí ọWọ́n ti hó lé ọ lórí;Má ṣe gbà wọ́n gbọ́bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ dáadáa.

Ka pipe ipin Jeremáyà 12