Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 11:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremáyà wá: láti ọ̀dọ̀ Olúwa:

2. “Fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí, kí o sì sọ wọ́n fún àwọn ènìyàn Júdà, àti gbogbo àwọn tó ń gbé ni Jérúsálẹ́mù.

3. Sọ fún wọn wí pé èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Ègbé ni fún ẹni náà tí kò pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí mọ́.

4. Àwọn májẹ̀mú tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, nígbà tí mo mú wọn jáde láti Éjíbítì, láti ìléru ìyọ́rin wá.’ Mo wí pé, ‘Ẹ gbọ́ tèmi, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo pa láṣẹ fún un yín. Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ènìyàn mi: Èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run yín

5. Nígbà náà ni Èmi ó sì mú ìlérí tí mo búra fún àwọn baba ńlá yín ṣẹ; láti fún wọn ní ilẹ̀ tí ó ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin,’ ilẹ̀ tí ẹ ní lónìí.”Mo sì dáhùn wí pé, “Àmí, Olúwa.”

6. Olúwa wí fún mi pé, “Kéde gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní àwọn ìlú Júdà àti ní ìgboro Jérúsálẹ́mù pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ìlérí yìí, kí ẹ sì máa tẹ̀lé wọn.

7. Láti ìgbà tí mo ti mú àwọn baba yín jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá títí di òní, mo kìlọ̀ fún wọn lọ́pọ̀ ìgbà wí pé, “Ẹ gbọ́ tèmi.”

8. Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọ bi ara sí i dípò èyí wọ́n tẹ̀ṣíwájú ni agídí ọkàn wọn. Mo sì mú gbogbo ègún inú májẹ̀mú tí mo ti ṣèlérí, tí mo sì ti pàṣẹ fún wọn láti tẹ̀lé, tí wọn kò tẹ̀lé.’ ”

Ka pipe ipin Jeremáyà 11