Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 6:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní pọ̀ si ní orí ilẹ̀, wọ́n sí i bí àwọn ọmọbìnrin.

2. Àwọn ọmọ Ọlọ́run rí i wí pé àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lẹ́wà, wọ́n sì fẹ́ èyíkéyìí tí ó wù wọ́n ṣe aya.

3. Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Èémí ìyè tí mo mí sínú ènìyàn kò ní máa gbé inú ènìyàn títí láé, nítorí ẹran ara ṣáà ni òun, ọgọ́fà ọdún, ni ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́.”

4. Àwọn òmìrán wà láyé ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti lẹ́yìn ìgbà náà: nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run lọ bá àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lò pọ̀ tí wọ́n sì bímọ fún wọn. Àwọn náà ni ó di akọni àti olókìkí ìgbà náà.

5. Olúwa sì rí bí ìwà búburú ènìyàn ti ń gbilẹ̀ si, àti pé gbogbo èrò inú rẹ̀ kìkì ibi ni, ní ìgbà gbogbo.

6. Inú Olúwa sì bàjẹ́ gidigidi nítorí pé ó dá ènìyàn sí ayé, ọkàn rẹ̀ sì gbọgbẹ́.

7. Nítorí náà, Olúwa wí pé “Èmi yóò pa ènìyàn tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀, ènìyàn àti ẹranko, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí inú mi bàjẹ́ pé mo ti dá wọn.”

8. Ṣùgbọ́n, Nóà rí ojúrere Olúwa.

9. Wọ̀nyí ni ìtàn Nóà.Nóà nìkan ni ó jẹ́ olóòótọ́ àti aláìlábùkù ní ìgbà ayé rẹ̀, ó sì bá Ọlọ́run rìn.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 6