Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 50:13-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Wọ́n gbé e lọ sí ilẹ̀ Kénánì, wọ́n sì sin-ín sínú ihò àpáta tí ó wà ní oko Makipélà, ní tòsí i Mámúrè tí Ábúráhámù rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú lọ́wọ́ Éfúrónì ará Hítì, pẹ̀lú ilẹ̀ náà.

14. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti sìnkú baba rẹ̀ tan, Jóṣẹ́fù padà sí Éjíbítì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn mìíràn tí ó tẹ̀lé e lọ láti sin baba rẹ̀.

15. Nígbà tí àwọn arákùnrin Jósẹ́fù rí i pé baba wọn kú, wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ bí ó bá ṣe pé Jósẹ́fù sì fi wá sínú ńkọ́, tí ó sì fẹ́ gbẹ̀ṣan gbogbo aburú tí a ti ṣe sí i?”

16. Nítorí náà wọ́n ránṣẹ́ sí Jósẹ́fù wí pé, “Baba rẹ fi àṣẹ yìí sílẹ̀ kí ó tó lọ wí pé:

17. ‘Èyí ni kí ẹ̀yin kí ó sọ fún Jóṣẹ́fù: Mo bẹ̀ ọ́ kí o dáríjìn àwọn arákùnrin rẹ, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti aburú tí wọ́n ṣe sí ọ, èyí tí ó mú ibi bá ọ’. Nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run baba rẹ jìn wọ́n.” Nígbà tí iṣẹ́ ti wọ́n rán dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Jósẹ́fù sunkún.

18. Àwọn arákùnrin rẹ̀ wá, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n wí pé, “Ẹrú rẹ ni a jẹ́.”

19. Ṣùgbọ́n Jósẹ́fù wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, èmi ha wà ní ipò Ọlọ́run bí?

20. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ gbérò láti ṣe mi ní ibi, ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbérò láti fi ṣe rere tí ń ṣe lọ́wọ́ yìí; ni gbígba ẹ̀mi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn là.

21. Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù. Èmi yóò pèṣè fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín.” Ó tún fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó sì sọ ọ̀rọ̀ rere fun wọn.

22. Jósẹ́fù sì ń gbé ní Éjíbítì pẹ̀lú gbogbo ìdílé baba rẹ̀. Ó sì wà láàyè fún àádọ́fà (110) ọdún.

23. Ó sì rí ìran kẹta ọmọ Éfúrémù-Àwọn ọmọ Mákírì, ọmọkùnrin Mánásè ni a sì gbé le eékún Jósẹ́fù nígbà tí ó bí wọn.

24. Nígbà náà ni Jóṣẹ́fù wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Mo ti fẹrẹ kú, ṣùgbọ́n dájúdájú Ọlọ́run yóò wá sí ìrànlọ́wọ́ yín, yóò sì mú-un yín jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí lọ sí ilẹ̀ tí ó ti ṣèlérí ní ìbúra fún Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù.”

25. Jóṣẹ́fù sì mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì búra májẹ̀mu kan wí pé, “Dájúdájú Ọlọ́run yóò wá sí ìrànlọ́wọ́ yín, nígbà náà ni ẹ gbọdọ̀ kó egungun mi lọ́wọ́ kúrò ní ìhín.”

26. Báyìí ni Jóṣẹ́fù kú nígbà tí ó pé àádọ́fà (110) ọdún. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n se òkú rẹ̀ lọ́jọ̀ tan, a gbé e sí inú pósí ní Éjíbítì.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 50