Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 46:6-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Wọ́n tún kó àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun-ìní tí wọ́n ti ní láti ilẹ̀ Kénánì, Jákọ́bù àti gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì.

7. Ó kó àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ obìnrin-gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ lọ sí Éjíbítì.

8. Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (Jákọ́bù àti Ìran rẹ̀) tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ Éjíbítì:Rúbẹ́nì àkọ́bí Jákọ́bù.

9. Àwọn ọmọkùnrin Rúbẹ́nì:Ánókù, Pálù, Ésírónì àti Kámì

10. Àwọn ọmọkùnrin Símónì:Jémúélì, Jámínì, Óhádì, Jákínì, Ṣóhárì àti Ṣáúlì, tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọbìnrin ará Kénánì.

11. Àwọn ọmọkùnrin Léfì:Gáṣónì, Kóhátì àti Mérárì.

12. Àwọn ọmọkùnrin Júdà:Ẹ́rì, Ónánì, Ṣélà, Pérésì àti Ṣérà (ṣùgbọ́n Ẹ́rì àti Ónánì ti kú ní ilẹ̀ Kénánì).Àwọn ọmọ Pérésì:Ésírónì àti Ámúlù.

13. Àwọn ọmọkùnrin Ísákárì!Tólà, Pútà, Jásíbù àti Ṣímírónì.

14. Àwọn ọmọkùnrin Ṣébúlúnì:Ṣérédì, Élónì àti Jáhálélì.

15. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Líà tí ó bí fún Jákọ́bù ní Padani-Árámù yàtọ̀ fún Dínà ọmọbìnrin rẹ̀. Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ mẹ́talélọ́gbọ̀n. (35) lápapọ̀.

16. Àwọn ọmọkùnrin Gádì:,Ṣífónì, Ágì, Ṣúnì, Ésíbónì, Érì, Áródì, àti Árélì.

17. Àwọn ọmọkùnrin Ásérì:Ímínà, Íṣífà, Íṣífì àti Béríà. Arábìnrin wọn ni Ṣérà.Àwọn ọmọkùnrin Béríà:Ébérì àti Málíkíélì.

18. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Jákọ́bù bí nípaṣẹ̀ Ṣílípà, ẹni tí Lábánì fi fún Líà ọmọbìnrin rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìndínlógún (16) lápapọ̀.

19. Àwọn ọmọkùnrin Rákélì aya Jákọ́bù:Jósẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 46