Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 46:4-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Èmi yóò sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ lọ sí Éjíbítì, èmi yóò sì tún mú ọ pada wá. Ọwọ́ Jósẹ́fù fúnra rẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí.”

5. Nígbà náà ni Jákọ́bù kúrò ní Báá-Ṣébà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì mú Jákọ́bù bàbá wọn àti àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì kó wọn sí inú kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Fáráò fí ránsẹ́ fún ìrìn-àjò rẹ̀:

6. Wọ́n tún kó àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun-ìní tí wọ́n ti ní láti ilẹ̀ Kénánì, Jákọ́bù àti gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì.

7. Ó kó àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ obìnrin-gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ lọ sí Éjíbítì.

8. Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (Jákọ́bù àti Ìran rẹ̀) tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ Éjíbítì:Rúbẹ́nì àkọ́bí Jákọ́bù.

9. Àwọn ọmọkùnrin Rúbẹ́nì:Ánókù, Pálù, Ésírónì àti Kámì

10. Àwọn ọmọkùnrin Símónì:Jémúélì, Jámínì, Óhádì, Jákínì, Ṣóhárì àti Ṣáúlì, tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọbìnrin ará Kénánì.

11. Àwọn ọmọkùnrin Léfì:Gáṣónì, Kóhátì àti Mérárì.

12. Àwọn ọmọkùnrin Júdà:Ẹ́rì, Ónánì, Ṣélà, Pérésì àti Ṣérà (ṣùgbọ́n Ẹ́rì àti Ónánì ti kú ní ilẹ̀ Kénánì).Àwọn ọmọ Pérésì:Ésírónì àti Ámúlù.

13. Àwọn ọmọkùnrin Ísákárì!Tólà, Pútà, Jásíbù àti Ṣímírónì.

14. Àwọn ọmọkùnrin Ṣébúlúnì:Ṣérédì, Élónì àti Jáhálélì.

15. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Líà tí ó bí fún Jákọ́bù ní Padani-Árámù yàtọ̀ fún Dínà ọmọbìnrin rẹ̀. Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ mẹ́talélọ́gbọ̀n. (35) lápapọ̀.

16. Àwọn ọmọkùnrin Gádì:,Ṣífónì, Ágì, Ṣúnì, Ésíbónì, Érì, Áródì, àti Árélì.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 46