Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 46:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Báyìí ni Ísírẹ́lì mú ìrìn-àjò rẹ̀ pọ̀n pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ní, nígbà tí ó sì dé Báá-Ṣébà, ó rúbọ sí Ọlọ́run Ísáákì baba rẹ̀.

2. Ọlọ́run sì bá Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ ní ojú ìrán ní òru pé, “Jákọ́bù! Jákọ́bù!”Ó sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

3. Ọlọ́run sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run, Ọlọ́run baba rẹ, má ṣe bẹ̀rù láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Éjíbítì nítorí, èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá níbẹ̀.

4. Èmi yóò sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ lọ sí Éjíbítì, èmi yóò sì tún mú ọ pada wá. Ọwọ́ Jósẹ́fù fúnra rẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí.”

5. Nígbà náà ni Jákọ́bù kúrò ní Báá-Ṣébà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì mú Jákọ́bù bàbá wọn àti àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì kó wọn sí inú kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Fáráò fí ránsẹ́ fún ìrìn-àjò rẹ̀:

6. Wọ́n tún kó àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun-ìní tí wọ́n ti ní láti ilẹ̀ Kénánì, Jákọ́bù àti gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì.

7. Ó kó àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ obìnrin-gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ lọ sí Éjíbítì.

8. Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (Jákọ́bù àti Ìran rẹ̀) tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ Éjíbítì:Rúbẹ́nì àkọ́bí Jákọ́bù.

9. Àwọn ọmọkùnrin Rúbẹ́nì:Ánókù, Pálù, Ésírónì àti Kámì

10. Àwọn ọmọkùnrin Símónì:Jémúélì, Jámínì, Óhádì, Jákínì, Ṣóhárì àti Ṣáúlì, tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọbìnrin ará Kénánì.

11. Àwọn ọmọkùnrin Léfì:Gáṣónì, Kóhátì àti Mérárì.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 46