Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 42:12-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ó wí fún wọn pé, “Rárá! Ẹ wá láti wo àsírí ilẹ̀ wa ni”

13. Ṣùgbọ́n wọ́n tún dáhùn pé, “Arákùnrin méjìlá ni àwa ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ baba kan náà, tí ó ń gbé ní ilẹ̀ Kénánì. Èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa ń bẹ lọ́dọ̀ baba wa, ọ̀kan sì ti kú.”

14. Jósẹ́fù wí fún wọn pé, “Bí mo ti wí fún un yín náà ni: Ayọ́lẹ̀wò ni yín!

15. Èyí sì ni a ó fi dán-an yín wò, èmi búra pé, níwọ̀n ìgbà tí Fáráò bá wà láàyè, ẹ kì yóò kùró níbí, àyàfi bí arákùnrin yín kan tókù bá wá síbí.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 42