Ṣùgbọ́n wọ́n tún dáhùn pé, “Arákùnrin méjìlá ni àwa ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ baba kan náà, tí ó ń gbé ní ilẹ̀ Kénánì. Èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa ń bẹ lọ́dọ̀ baba wa, ọ̀kan sì ti kú.”