Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 31:24-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Ọlọ́run sì yọ sí Lábánì ará Arámáínì lójú àlá ní òru, ó sì wí fun un pé, “Ṣọ́ra, má ṣe sọ ohunkóhun fún Jákọ́bù, ìbá à ṣe rere tàbí búburú.”

25. Jákọ́bù ti pa àgọ́ rẹ̀ si orí òkè kan, nígbà tí Lábánì bá a. Lábánì àti àwọn tí ó wá pẹ̀lú rẹ̀ sì pàgọ́ tiwọn sí ilẹ̀ òkè Gílíádì.

26. Nígbà náà ni Lábánì wí fún Jákọ́bù pé, “Èwo ni ìwọ ṣe yìí? Tí ìwọ sì tàn mi, ó sì kó àwọn ọmọbìnrin mi bi ìgbékùn tí a mú lógun.

27. Èéṣe tí ìwọ yọ́ lọ tí ìwọ sì tàn mi? Kín ló dé tí ìwọ kò sọ fún mi pé ìwọ ń lọ, kí èmi fi ayọ̀ sìn ọ, pẹ̀lú orin àti ohun èlò orin.

28. Ìwọ kò tilẹ̀ jẹ́ kí èmi fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ mi lẹ́nu, pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin mi pé ó dìgbà? Ohun tí ìwọ ṣe yìí jẹ́ ìwà òmùgọ.

29. Mo ní agbára láti ṣe ọ ni ibi, ṣùgbọ́n ní òru àná, Ọlọ́run baba rẹ sọ fún mi pé, kí èmi ṣọ́ra, kí èmi má ṣe sọ ohun kan fún ọ, ìbáà ṣe rere tàbí búburú.

30. Nísin yìí, ìwọ ti lọ nítorí ìwọ fẹ́ lati padà lọ sí ilé baba rẹ, ṣùgbọ́n èéṣe tí ìwọ fi jí àwọn òrìṣà mi?”

31. Jákọ́bù dá Lábánì lóhùn pé, “Ẹ̀rù ni ó bà mi nítorí, mo rò pé ìwọ le fi tipá tipá gba àwọn ọmọbìnrin rẹ lọ́wọ́ mi.”

32. “Ṣùgbọ́n bí o bá ri ẹnikẹ́ni pẹ̀lú ère rẹ, kí ẹni náà di òkú.” Ó tún wí pé, “Níwájú gbogbo ìbátan wa báyìí, wò ó fúnra rẹ, bí o bá rí ohunkóhun tí í ṣe tìrẹ, mú un.” Jákọ́bù kò sì mọ̀ pé, Rákélì ni ó jí àwọn òrìṣà náà.

33. Lábánì sì lọ sínú àgọ́ Jákọ́bù àti ti Líà àti ti àwọn ìránṣẹ́-bìnrin méjèèjì, kò sì rí ohunkóhun. Lẹ́yìn ìgbà tí ó jáde nínú àgọ́ Líà ni ó lọ sí àgọ́ Rákélì.

34. Rákélì sì gbé àwọn òrìṣà náà sínú gàárì ràkunmí, ó sì jókòó lé e lórí. Lábánì sì wá gbogbo inú àgọ́, kò sì rí ohunkóhun.

35. Rákélì sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Má ṣe bínú pé èmi ò le dìde dúró níwájú rẹ bàbá à mi, ohun tí ó fà á ni pé, mò ń ṣe nǹkan oṣù lọ́wọ́.” Ó sì wá àgọ́ kiri, kò sì rí àwọn òrìṣà-ìdílé náà.

36. Inú sì bí Jákọ́bù, ó sì pe Lábánì ní ìjà pé, “Kín ni ẹ̀ṣẹ̀ mi? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ tí ìwọ fi ń lépa mi bí ọ̀daràn?

37. Nísinsin yìí tí ìwọ ti tú gbogbo ẹrù mi wò, kín ni ohun tí í ṣe tirẹ̀ tí ìwọ rí? Kó wọn kalẹ̀ báyìí níwájú gbogbo ìbátan rẹ àti tèmi, kí wọn kí ó sì ṣe ìdájọ́ láàrin àwa méjèèjì.

38. “Mo ti wà lọ́dọ̀ rẹ fún ogún ọdún, àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́ rẹ kò sọnù bẹ́ẹ̀ n kò pa ọ̀kan jẹ rí nínú àwọn àgbò rẹ.

39. Èmi kò mú ọ̀kankan wá fún ọ rí nínú èyí tí ẹranko búburú fà ya, èmi ni ó fara mọ́ irú àdánù bẹ́ẹ̀. Ẹrankẹ́ran tí wọ́n bá sì jí lọ, lọ́sàn án tàbí lóru, ìwọ ń gba owó rẹ̀ lọ́wọ́ mi

40. Báyìí ni mo wà; oòrùn ń pa mi lọ́sàn-án, òtútù ń pa mi lóru, mo sì ń ṣe àìsùn.

41. Báyìí ni ohun gbogbo rí fún ogún ọdún tí mo fi wà nínú ilé rẹ. Ọdún mẹ́rìnlá ni mo fi sìn ọ́ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì, mo sì sìn ọ fún ọdún mẹ́fà fún àwọn ẹran ọ̀sìn, lẹ́ẹ̀mẹ́wàá ni o sì yí owó iṣẹ́ mi padà.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 31