Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 24:1-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ábúráhámù sì ti darúgbó ní àkókò yìí, Olúwa sì ti bùkún fún-un ni gbogbo ọ̀nà,

2. Ó wí fún olórí àwọn ìránṣẹ́ ilẹ̀ rẹ̀, tí ó jẹ́ alábojútó ohun gbogbo tí ó ní pé, “Fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi.

3. Èmi yóò mú ọ búra lórúkọ Olúwa Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ kì yóò fẹ́ aya fún ọmọ mi nínú àwọn ọmọbìnrin ará Kénánì, láàrin àwọn ẹni tí èmi ń gbé.

4. Ṣùgbọ́n, ìwọ yóò lọ sí orílẹ̀-èdè mi, láàrin àwọn ará mi láti fẹ́ aya fún Ísáákì, ọmọ mi.”

5. Ìránṣẹ́ náà bi í wí pé, “Ǹjẹ́ bí ọmọbìnrin náà bá kọ̀ láti bá mi wá sí ilẹ̀ yìí ń kọ́? Ǹjẹ́ mo lè mú ọmọ rẹ padà lọ sí orílẹ̀-èdè níbi tí ìwọ ti wá?”

6. Ábúráhámù sì wí fún un pé, “Rí i dájú pé iwọ kò mú ọmọ mi padà lọ sí ibẹ̀.”

7. “Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run tí ó mú mi jáde láti ilẹ̀ baba mi àti ní ilẹ̀ tí a bí mi, tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tí ó sì búra fún mi pé, ‘Irú ọmọ rẹ ni n ó fi ilẹ̀ yìí fún’, yóò rán ańgẹ́lì rẹ̀ ṣáájú rẹ, kí ìwọ kí ó lè rí aya fẹ́ wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀.

8. Bí obìnrin náà kò bá fẹ́ tẹ̀lé ọ wá, nígbà náà ni a tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ìbúra yìí, ṣùgbọ́n pàtàkì ni pé ìwọ kò gbọdọ̀ mú ọmọ mi padà lọ sí ibẹ̀.”

9. Ìránṣẹ́ náà sì fi ọwọ́ rẹ̀ sí abẹ́ itan Ábúráhámù olúwa rẹ̀, ó sì búra fún nítorí ọ̀rọ̀ náà.

10. Ìránṣẹ́ náà sì mú ràkunmí mẹ́wàá, pẹ̀lú onírúurú ohun dáradára láti ọ̀dọ̀ olúwa rẹ̀, ó sì dìde ó sì lọ sí Aramu-Náháráímù, sí ìlú Náhórì,

11. Ó sì mú àwọn ràkunmí náà kúnlẹ̀ nítòòsí kànga lẹ́yìn ìlú, ó ti ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ̀ ní àkókò tí àwọn obìnrin máa ń lọ pọn omi.

12. Ó sì gbàdúrà wí pé, “Olúwa, Ọlọ́run Ábúráhámù olúwa à mi; jẹ́ kí n ṣe àṣeyọrí lónìí, sì fi àánú hàn fún Ábúráhámù olúwa mi.

13. Kíyèsí i, mo dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ yìí, àwọn ọmọbìnrin ìlú yìí sì ń jáde wá pọn omi.

14. Jẹ́ kí ó ṣe pé nígbà tí mo bá wí fún ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin pe, ‘Jọ̀wọ́ sọ ládugbó rẹ kalẹ̀, kí n le mu omi,’ tí ó bá sì wí pé, ‘mu un, èmi ó sì fún àwọn ràkunmí rẹ náà mu pẹ̀lú,’ jẹ́ kí ó ṣe èyí tí o yàn fún ìránṣẹ́ rẹ Ísáákì. Nípa èyí ni n ó fi mọ̀ pé o ti fi àánú hàn fún olúwa mi.”

15. Kí o tó di pé, ó parí àdúrà, Rèbékà dé pẹ̀lú ìkòkò omi rẹ̀ ní èjìká rẹ̀. Ọmọ Bétúélì ni. Bétúélì yìí ni Mílíkà bí fún Náhórì arákùnrin Ábúráhámù.

16. Ọmọbìnrin náà rẹwà, wúndíá ni, kò sì tíì mọ ọkùnrin, ó lọ sí ibi ìsun omi náà, ó sì pọn omi sínú ìkòkò omi, ó sì gbé e, ó ń gòkè bọ̀ kúrò níbi omi.

17. Ìránṣẹ́ náà súré lọ pàdé e rẹ̀ ó sì wí fun un pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ni omi díẹ̀ nínú ìkòkò omi rẹ.”

18. Òun náà dáhùn pé, “Mu, olúwa mi,” ó sì yára sọ ìkòkò omi náà ka ọwọ́ rẹ̀, ó sì fún-un mu.

19. Lẹ́yìn tí ó ti fún un ni omi mu tán, ó wí pé, “Èmi ó bu omi fún àwọn ràkunmí rẹ pẹ̀lú títí wọn yóò fi mu àmutẹ́rùn.”

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 24