Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 18:19-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Nítorí tí èmi ti yàn án láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ará ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, láti máa pa ọ̀nà Olúwa mọ nípa ṣíṣe olóòtọ́ àti olódodo: kí Olúwa le è mú ìlérí rẹ̀ fún Ábúráhámù ṣẹ.”

20. Olúwa sì wí pé, igbe Ṣódómù àti Gòmórà pọ̀ púpọ̀ àti pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn burú jọjọ.

21. “Èmi yóò sọ̀kalẹ̀ síbẹ̀ láti ṣe ìwádìí igbe tí ó dé sí etí ìgbọ́ mi nípa wọn, kí èmi sì mọ òtítọ́ tí ó wà níbẹ̀.”

22. Àwọn ọkùnrin náà yí padà, wọ́n sì ń lọ sí ìhà Ṣódómù. Ṣùgbọ́n Ábúráhámù dúró níbẹ̀ níwájú Olúwa.

23. Nígbà náà ni Ábúráhámù súnmọ́ ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì wí pé, “Ìwọ yóò ha pa ènìyàn rere àti ènìyàn búrurú run papọ̀ bí?”

24. “Bí ó bá ṣe pé Ìwọ rí àádọ́ta olódodo nínú ìlú náà, Ìwọ yóò ha run-ún, Ìwọ kì yóò ha dá ìlú náà sí nítorí àwọn àádọ́ta olódodo tí ó wà nínú rẹ̀ náà?

25. Kò jẹ́ rí bẹ́ẹ̀! Dájúdájú Ìwọ kì yóò ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀, láti pa olódodo pẹ̀lú àwọn ènìyàn rere àti àwọn ènìyàn búburú. Dájúdájú Ìwọ kì yóò ṣe èyí tí ó tó bi?”

26. Olúwa wí pé, “Bí mo bá rí àádọ́ta (150) olódodo ní ìlú Ṣódómù, èmi yóò dá ìlú náà sí nítorí tí wọn.”

27. Ábúráhámù sì tún tẹ̀ṣíwájú pé, “Wò ó nísinsin yìí, níwọ̀n bí èmi ti ní ìgboyà láti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ níwájú sí Olúwa, èmi ẹni tí í ṣe erùpẹ̀ àti eérú,

28. bí ó bá ṣe pe olódodo márùn-dín-làádọ́ta (45) ni ó wà nínú ìlú, Ìwọ yóò ha pa ìlú náà run nítorí ènìyàn márùn-ún bí?” Olúwa dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo márùn-dín-láàádọ́ta nínú rẹ̀.”

29. Òun sì tún wí lẹ́ẹ̀kan si pé, “Bí ó bá ṣe pé ogójì (40) ni ńkọ́?” Olúwa sì tún wí pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo ogójì nínú rẹ̀.”

30. Ábúráhámù sì tún bẹ Olúwa pé, “Kí Olúwa má ṣe bínú, ṣùgbọ́n èmi yóò sọ̀rọ̀. Bí ó bá ṣe pé ọgbọ̀n (30) ni rí níbẹ̀ ńkọ́?” Olúwa dáhùn pé, “Bí mó bá rí ọgbọ̀n, Èmi kì yóò pa ìlú run.”

31. Ábúráhámù wí pé, “Níwọ̀n bí mo ti ní ìgboyà láti bá Olúwa sọ̀rọ̀ báyìí, jẹ́ kí n tẹ̀ṣíwájú. Bí o bá ṣe pé olódodo ogún péré ni ó wà nínú ìlú náà ńkọ́?” Olúwa sì dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa á run nítorí ogún ènìyàn náà.”

32. Ábúráhámù sì wí pé, “Jọ̀wọ́ má ṣe bínú Olúwa. Jẹ́ kí ń béèrè lẹ́ẹ̀kan si. Bí ó bá ṣe pé ènìyàn mẹ́wàá ni bá tí ó jẹ́ olódodo ńkọ́?” Olúwa wí pé, “Nítorí ènìyàn mẹ́wàá náà, Èmi kì yóò pa á run.”

33. Olúwa sì bá tirẹ̀ lọ, nígbà tí ó bá Ábúráhámù sọ̀rọ̀ tan, Ábúráhámù sì padà sílé.

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 18