Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹ́nẹ́sísì 1:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé.

2. Ayé sì wà ní rúdurùdu, ó sì ṣófo, òkùnkùn sì wà lójú ibú omi, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń rá bàbà lójú omi gbogbo.

3. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà,” ìmọ́lẹ̀ sì wà.

4. Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì ya ìmọ́lẹ̀ náà sọ́tọ̀ kúrò lára òkùnkùn.

5. Ọlọ́run sì pe ìmọ́lẹ̀ náà ní “Ọ̀sán” àti òkùnkùn ní “Òru.” Àsálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní.

6. Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí òfuurufú kí ó wà ní àárin àwọn omi láti pààlà sí àárin àwọn omi.”

7. Ọlọ́run sì dá òfuurufú láti ya omi tí ó wà ní òkè òfuurufú kúrò lára omi tí ó wà ní orí ilẹ̀. Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

8. Ọlọ́run sì pe òfúurufú ní “Ọ̀run,” àsálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kejì.

9. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojúkan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

10. Ọlọ́run sì pe ilẹ̀ gbígbẹ náà ní “Ilẹ̀” àti àpapọ̀ omi ní “Òkun:” Ọlórun sì rí i wí pé ó dára.

11. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó hu ọ̀gbìn: ewéko ti yóò máa mú èṣo wá àti igi tí yóò máa so èṣo ní irú tirẹ̀, tí ó ní irúgbìn nínú.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

12. Ilẹ̀ sì hù ọ̀gbìn: ewéko tí ó ń so èṣo ní irú tirẹ̀, àti igi tí ń so èṣo, tí ó ní irúgbìn nínú ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì ri pé ó dára.

13. Àsálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kẹta.

14. Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, làti pààlà sí àárin ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún àmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún,

Ka pipe ipin Jẹ́nẹ́sísì 1