Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, làti pààlà sí àárin ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún àmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún,