Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 9:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mo gbọ́ tó kígbe pé, “Mú àwọn olùṣọ́ ìlú súnmọ́ ìtòsí, kí olúkúlùkù wọn mú ohun ìjà olóró lọ́wọ́.”

2. Lójú ẹsẹ̀ ni ọkùnrin mẹ́fà (6) jáde láti ẹnu ọ̀nà òkè tó kọjú sí ìhà àríwá, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà olóró lọ́wọ́ wọn. Ọkùnrin kan tó wọ aṣọ funfun lẹlẹ wa láàrin wọn, pẹ̀lú ohun ìkọ̀we lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Gbogbo wọn sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ idẹ.

3. Ògo Ọlọ́run sì gòkè kúrò lórí Kérúbù, níbi tó wà tẹ́lẹ̀ lọ síbi ìloro tẹ́ḿpìlì. Nígbà náà ni Olúwa pe ọkùnrin tó wọ aṣọ funfun lẹlẹ tí ó sì ní ohun ìkọ̀wé lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

4. Ó sì sọ fún un pé, “La àárin ìlú Jérúsálẹ́mù já, kí o sì fi àmì síwájú orí gbogbo àwọn tó ń kẹ́dùn, tó sì ń sunkún nítorí ohun ìríra tí wọn ń ṣe láàrin rẹ̀.”

5. Bí mo ṣe ń fetí sí èyí, O tún sọ fún àwọn yòókù pé, “Tẹ̀lé ọkùnrin náà lọ sáàrin ìlú láti pa láì dásí àti láì ṣàánú rárá.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 9