Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 48:28-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. “Ààlà tí gúsù Gádì yóò dé gúsù láti Támárì lọ sí odò Méríbà Kádésì lẹ́yìn náà títí dé Wádì ti Éjíbítì lọ sí òkun ńlá fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ìwọ̀nyí ní yóò sì jẹ́ ìpín wọn” ní Olúwa Ọba wí.

29. “Èyí ni ilẹ̀ tí ẹ̀yin o fi ìbò pín ní ogún fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, wọ̀nyí sì ni ìpín wọn,” ní Olúwa Ọlọ́run wí.

30. “Ìwọ̀nyí ní yóò jẹ́ ẹnu ọ̀nà àbájáde ìlú ńlá náà: Bẹ̀rẹ̀ láti ìhà àríwá, ti ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn,

31. ẹnu ọ̀nà ìlú ńlá náà ní àwa yóò fi orúkọ àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì pè. Àwọn ọ̀nà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ní ìhà àríwá ní yóò jẹ́ ọ̀nà tí Rúbẹ́nì, ọ̀nà tí Júdà ọ̀nà tí Léfì

32. “Ní ìhà ìlà oòrùn, èyí tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ni ojú ọ̀nà mẹ́ta yóò wà: ọ̀nà Jósẹ́fù, ọ̀nà tí Bẹ́ńjámínì àti ọ̀nà tí Dánì.

33. “Ní ìhà gúsù, èyí tí wíwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ ní ojú ọ̀nà mẹ́ta yóò wà: ojú ọ̀nà Símónì, ojú ọ̀nà Ísákárì àti ojú ọ̀nà Sébúlónì.

34. “Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, èyí tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ní ojú ọ̀nà mẹ́ta yóò wà: ojú ọ̀nà Gádì, ojú ọ̀nà Ásárì àti ojú ọ̀nà Náfítalì.

35. “Jíjnìnà rẹ̀ yípo yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) ìgbọ̀nwọ́.“Orúkọ ìlú náà láti ìgbà náà yóò jẹ́: Olúwa wà níbẹ̀.”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 48