Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 48:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà tí a kọ sílẹ̀ pẹ̀lú orúkọ wọn: Ní òpin àríwá, Dánì yóò ni ìpín kan; èyí yóò tẹ̀lé ọ̀nà Hétílónù sí létí Hámátì; Hásárì Énánù àti ààlà àríwá tí Dámásíkù tí ó kángun sí Hámátì yóò jẹ́ ara ààlà rẹ̀ láti ìhà ìlà oòrùn títí lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn.

2. “Àsárì yóò ní ìpín kan; yóò jẹ́ ààlà agbégbé dánì láti ìlà oòrùn lọ sí ìwọ oòrùn.

3. “Náfítalì yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbégbé Ásárì láti ìlà oòrùn lọ sí ìwọ̀ oòrùn.

4. “Mánásè yóò ní ìpín; èyí yóò jẹ́ ààlà ti agbégbé Náfátalì láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn.

5. “Éfúráímù yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbégbé Mánásè láti ìlà oòrùn lọ sí ìwọ oòrùn.

6. “Rúbẹ́nì yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbégbé Éfúráímù láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

7. “Júdà yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbégbé Rúbẹ́nì láti ìlà oòrùn lọ sí ìwọ̀ oòrùn.

8. “Ààlà agbégbé Júdà láti ìlà oòrùn dé ìwọ̀ oòrùn yóò jẹ́ ìpín tí ìwọ yóò gbé kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pàtàkì. Yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ (25,000) ní fífẹ̀, gígùn rẹ̀ láti ìlà oòrùn lọ sí ìwọ̀ oòrùn yóò jẹ́ bákan náà pẹ̀lú àwọn ìpín ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan; ilé mímọ́ yóò wà ní àárin gbùngbùn rẹ̀.

9. “Ìpín pàtàkì tí ìwọ yóò fifún Olúwa yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25,000) ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 48