Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 46:19-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi kọjá ní àbáwọlé tí ó wà lẹ́bá ẹnu ọ̀nà, sí àwọn yàrá mímọ́ tí ó kọjú sí ìhà àríwá, èyí tí ó jẹ́ tí àwọn àlùfáà, ó sì fi ibi kan hàn mí ní apá ìwọ̀ oòrùn.

20. O sọ fún mi pé, “Èyí yìí ni ibi tí àwọn àlùfáà yóò ti ṣe ọrẹ ẹbọ ìdálẹ́bi àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti tí wọn yóò ṣe ọrẹ ẹbọ jíjẹ, láti má se jẹ́ kí wọn mú wọn wá sí ìta àgbàlá kí wọn sì ya àwọn ènìyàn sí mímọ́.”

21. Ó sì mú mi lọ sí ìta àgbàlá, ó sì mú mi yí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ká, mo sì ri àgbàlá mìíràn ní igun kọ̀ọ̀kan.

22. Ní ìgun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìta àgbàlá tí ó pẹnupọ̀, ogójì ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn àti ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀; àgbàlá kọ̀ọ̀kan ni igun kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìwọ̀n kan náà.

23. Ní agbègbè inú ikọ̀ọ̀kan nínú àgbàlá náà ni ọwọ́ ilẹ̀ kan wà yíká wọn, a sì ṣe ibi ìdáná si abẹ́ ọwọ́ náà yípo.

24. Ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ̀nyí ni àwọn ilé ìdáná níbi tí o ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú tẹ́ḿpìlì yóò ti ṣe ẹbọ fún àwọn ènìyàn.”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 46