Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 46:13-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. “ ‘Ní ojoojúmọ́ ni ìwọ yóò pèsè ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa; àràárọ̀ ni ìwọ yóò máa pèsè rẹ̀.

14. Ìwọ yóò sì máa pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ pẹ̀lú rẹ̀ ní àràárọ̀, èyí yóò ni ìdámẹ́fà nínú éfà àti ìdámẹ́fà nínú òróró hínì láti fi po ìyẹ̀fun. Gbígbé ọrẹ ẹbọ jíjẹ fún Olúwa jẹ́ ìlànà tí ó wà títí.

15. Nítorí náà ọ̀dọ́ àgùntàn àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti òróró ni wọn yóò pèsè ní àràárọ̀ fún ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo.

16. “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Ọba sọ: Tí ọmọ aládé bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, yóò jẹ́ ìní tíwọn nípa ogún jíjẹ.

17. Tí ó bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọkan lára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ọmọ le pa mọ́ títí di ọdún ìdásílẹ̀; Lẹ́yìn náà yóò padà sí ọ̀dọ̀ ọmọ aládé. Ogún ìní rẹ̀ jẹ́ ti àwọn ọmọ rẹ̀ nìkan; Ó jẹ́ tiwọn.

18. Ọmọ aládé kò gbọdọ̀ mú ìkankan lára ogún ìní àwọn ènìyàn, tàbí mú wọn kúrò níbi ohun ìní wọn. Ó ní láti fi ogún ìní rẹ̀ láti inú ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kí a ma baà ya ìkankan kúrò lára ìní rẹ̀’ ”

19. Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi kọjá ní àbáwọlé tí ó wà lẹ́bá ẹnu ọ̀nà, sí àwọn yàrá mímọ́ tí ó kọjú sí ìhà àríwá, èyí tí ó jẹ́ tí àwọn àlùfáà, ó sì fi ibi kan hàn mí ní apá ìwọ̀ oòrùn.

20. O sọ fún mi pé, “Èyí yìí ni ibi tí àwọn àlùfáà yóò ti ṣe ọrẹ ẹbọ ìdálẹ́bi àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti tí wọn yóò ṣe ọrẹ ẹbọ jíjẹ, láti má se jẹ́ kí wọn mú wọn wá sí ìta àgbàlá kí wọn sì ya àwọn ènìyàn sí mímọ́.”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 46