Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 46:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Ọba wí Ẹnu ọ̀nà àgbàlá ti inú tí ó dojúkọ ìhà ìlà oòrùn ni kí a tì pa fún ọjọ́ mẹ́fà tí a fi ń ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ìsinmí àti ní ọjọ́ oṣù tuntun ni kí a sí i.

2. Ọmọ aládé ni kí ó wọlé láti ìta tí ó kangun sí àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà, kí ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà. Àwọn àlùfáà ni yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ ìdàpọ̀. Òun ni yóò jọ́sìn ní ìloro ilé ní ẹnu ọ̀nà, lẹ́yìn náà ni wọn yóò jáde, ṣùgbọ́n wọn kò ni ti ilẹ̀kùn títí ìrọ̀lẹ́.

3. Ní àwọn ọjọ́ ìsinmi àti àwọn oṣù tuntun ni kí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà jọ́sìn ní iwájú Olúwa ní àbáwọlé ẹnu ọ̀nà.

4. Ọrẹ ẹbọ sísun tí ọmọ aládé mú wá fún Olúwa ni ọjọ́ ìsinmí ní láti jẹ́ ọ̀dọ́ àgbò mẹ́fà àti àgbò kan, gbogbo rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù.

5. Ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú papọ̀ mọ́ àgbò gbọdọ̀ jẹ́ éfà kan, ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn ni kí ó pò gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe fẹ́, papọ̀ mọ hínì òróró kan pẹ̀lú éfà kọ̀ọ̀kan.

6. Àti ni ọjọ́ oṣù tuntun, ẹgbọrọ màlúù kan àìlábàwọ́n, àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́fà, àti àgbò kan: wọn o wà láìlábàwọ́n.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 46