Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 43:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi gba ti ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà oòrùn,

2. mo sì ri ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì ń bọ láti ìhà ìlà oòrùn. Ohùn rẹ̀ dàbí híhó omi, ìtànsán ògo rẹ̀ sì bo ilẹ̀.

3. Ìran tí mo rí dàbí ìran tí mo rí lẹ́bàá odò Kébárì, mo sì dorí kodò.

4. Ògo Olúwa gba ọ̀nà tí o dojúkọ ìhà ìlà oòrùn wọ inú ilé Ọlọ́run wá.

5. Mo ni ìrusókè ẹ̀mí, ó sì mú mi lọ inú ilé ìdájọ́, sì kíyèsí ògo Olúwa kún inú ilé Ọlọ́run.

6. Nígbà tí ọkùnrin náà dúró ní ẹ̀gbẹ́ mi, mo gbọ́ ẹnìkan tí ó bá mi sọ̀rọ̀ láti inú ilé Ọlọ́run.

7. Ó sì wí pé: “Ọmọ ènìyàn, èyí yìí ni ibi ìgunwà mi àti ibi tí ó wà fún àtẹ́lẹsẹ̀ mi, Ibi yìí ni èmi yóò máa gbé ní àárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí láéláé. Ilé Ísírẹ́lì kò ní ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́ láéláé àwọn tàbí àwọn Ọba wọn nípa àgbèrè àti àwọn ère aláìlẹ́mìí àwọn Ọba wọn ní ibi gíga.

8. Nígbà tí wọ́n ba gbé ìlóro ilé wọn kangun sí ìlóro ilé mi àti ìlẹ̀kùn wọn sì ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀kùn mi, pẹ̀lú ògiri nìkan ní àárin èmi pẹ̀lú wọn, wọ́n ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú ìwà ìríra wọn. Nígbà náà ni mo pa wọ́n run ní ìbínú mi.

9. Nísinsin yìí jẹ́ kí wọn mú ìwà àgbérè wọn àti àwọn ère aláìlẹ́mìí àwọn Ọba wọn kúrò ni iwájú mi, èmi yóò sì gbé àárin wọn láéláé.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 43