Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 43:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi gba ti ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà oòrùn,

2. mo sì ri ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì ń bọ láti ìhà ìlà oòrùn. Ohùn rẹ̀ dàbí híhó omi, ìtànsán ògo rẹ̀ sì bo ilẹ̀.

3. Ìran tí mo rí dàbí ìran tí mo rí lẹ́bàá odò Kébárì, mo sì dorí kodò.

4. Ògo Olúwa gba ọ̀nà tí o dojúkọ ìhà ìlà oòrùn wọ inú ilé Ọlọ́run wá.

5. Mo ni ìrusókè ẹ̀mí, ó sì mú mi lọ inú ilé ìdájọ́, sì kíyèsí ògo Olúwa kún inú ilé Ọlọ́run.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 43