Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 42:14-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ní wọ̀n ìgbà tí àwọn àlùfáà bá ti wọ aṣọ funfun ibi mímọ́, wọn kò gbọdọ̀ lọ sí ìta ilé ìdájọ́ àfi tí wọ́n bá bọ àwọn aṣọ tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ ìsin sílẹ̀ ní ibi tí wọn tí lò ó, nítorí wọ́n jẹ́ mímọ́. Wọn gbọdọ̀ wọ aṣọ mìíràn kí wọn tó sún mọ́ ibi tí àwọn ènìyàn yòókù máa ń wà.”

15. Nígbà tí o parí nǹkan tí ó wà nínú ilé Ọlọ́run tán, o mú mi jáde lọ sí ọ̀nà tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, ó sì wọn agbégbé náà yípo:

16. Ó wọn ìhà ìlà oòrùn pẹ̀lú ọ̀pá ìwọ̀n ǹnkan; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́.

17. Ó wọn ìhà àríwá; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pá ìwọn nǹkan.

18. O wọn ìhà gúsù; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pá wíwọ̀n nǹkan.

19. Lẹ́yìn èyí ni ó wà yí padà sí ìhà ìwọ̀ oòrùn o sì wọ̀n ọ́n: ó sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pa wíwọ̀n.

20. Báyìí ní ó wọn agbégbé ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Ó ní ògiri kan yípo rẹ̀, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀, àti ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, láti ya ibi mímọ́ sọ́tọ̀ kúrò ní ibi tí gbogbo ènìyàn ń lọ sọ́tọ̀.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 42