Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 4:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Nísinsìnyìí, Ìwọ ọmọ ènìyàn, mú amọ̀ ṣíṣù kan, gbé e sí iwájú rẹ, kí o sì ya àwòrán Jérúsálẹ́mù sí orí rẹ̀.

2. Kí o sì dó tì í, kí o sì mọ ilé ìṣọ́ tì í, kí o sì mọ odi tì í, kí o sì gbé ogun sí i, kí o sì to òòlù yí i ká.

3. Kí o sì fi páànù irin kan ṣe ògiri láàrin rẹ̀ àti ìlú yìí, dojú kọ ọ́, kí o sì gbógun tì í. Èyí yóò jẹ́ àmì fún ilé Ísírẹ́lì.

4. “Lẹ́yìn èyí, lọ fi ẹ̀gbẹ́ òsì dúbúlẹ̀, kí o sì gbé ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì lé orí ara rẹ. Iye ọjọ́ tí ìwọ bá fi sùn náà ni ìwọ yóò fi ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

5. Nítorí mo fi iye ọdún tí wọ́n fi ṣẹ̀ fún ọ gẹ́gẹ́ bí iye ọjọ́ tí ìwọ yóò lò. Nítorí náà, ìwọ yóò ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390).

6. “Tí o bá parí èyí, tún fi ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún dùbúlẹ̀ kí o sì ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Júdà fún ogójì (40) ọjọ́, nítorí pé ọjọ́ kan ló dúró fún ọdún kan.

7. Dojú kọ ibùdó ogun Jérúsálẹ́mù, na ọwọ́ rẹ sí i, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìlú náà.

8. Èmi yóò dè ọ́ ní okùn débi pé ìwọ kò ní í le yírapadà láti ìhà ọ̀tún sí ìhà òsì títí tí ọjọ́ ìgbógun tì rẹ yóò fi pé.

9. “Mú ọkà bàbà àti àlìkámà, erèé àti lẹ́ńtìlì, jéró àti ẹwẹ; fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe àkàrà tí ìwọ yóò máa jẹ nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀ fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá.

10. Wọn òṣùnwọ̀n ogún (20) ṣékélì oúnjẹ tí ìwọ yóò máa jẹ-lójoojúmọ́ kí o sì máa jẹ ẹ́ ní àkókò tí a ti yà sọ́tọ̀.

11. Bákan náà, wọn ìdámẹ́fà hínì omi, kí ìwọ ó sì máa mú ní àkókò tí a yà sọ́tọ̀.

12. Ìwọ yóò sì jẹ ẹ́ bí àkàrà báálì; dín in ní ojú àwọn ènìyàn, ìgbẹ́ ènìyàn ni kí o fi dáná rẹ.”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 4