Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 36:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀ sí àwọn òkè gíga Ísírẹ́lì kí o sì wí pé, ‘Ẹ̀yin òkè gíga Ísírẹ́lì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.

2. Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Àwọn ọ̀tá sọ nípa yín pé, “Áà! Àwọn ibi gíga ìgbàanì ti di ohun ìní wa.” ’

3. Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Nítorí pé wọn sọ ọ di ahoro, tí wọn sì ń dọdẹ rẹ ní gbogbo ọ̀nà kí ìwọ kí ó lè di ìní fún àwọn orílẹ̀ èdè tí ó kù, àti ohun ti àwọn ènìyàn ń sọ ọ̀rọ̀ ìríra àti ìdibàjẹ́ sí,

4. nítorí náà, Ẹ̀yin òkè gíga Ísírẹ́lì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun: Èyí yìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí fún àwọn òkè gíga àti àwọn òkè kékèké, fún àfonífojì ńlá àti àfonífojì kékèké, fún àwọn ibi ìsọdahoro ìparun àti fún àwọn ìlú tí a ti kọ̀ sílẹ̀ tí a ti kó tí àwọn orílẹ̀ èdè tí ó kù ní àyíká sì fi ṣe ẹlẹ́yà

5. Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ní ìgbóná ọkàn ní mo sọ̀rọ̀ lòdì sí Édómù, nítorí pẹ̀lú ayọ̀ àti ìyodì ní ọkàn wọn ní wọ́n sọ ilé mi di ohun ìní wọn, kí wọn kí o lè kó pápá oko tútù rẹ̀.’

6. Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Ísírẹ́lì náà kí o sì sọ sí àwọn òkè gíga náà àti àwọn òkè kékèké, sí àwọn àfonífojì ńlá àti sí àwọn àfonífojì kéékèèkéé: ‘Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi sọ̀rọ̀ nínú ìrunú owú mi nítorí pé ìwọ ti jìyà ìfiṣẹ̀sín àwọn orílẹ̀ èdè.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 36