Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 34:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ́ mi wá:

2. “Ọmọ ènìyàn, fí àsọtẹ́lẹ̀ tako olùsọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì; sọ tẹ́lẹ̀ fún wọn pé: ‘Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ègbé ni fún olùsọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì tí ó ń tọ́jú ara wọn nìkan! Ṣé ó dára kí olùṣọ́ àgùntàn ṣaláì tọ́jú agbo ẹran?

3. Ìwọ jẹ wàrà. O sì wọ aṣọ olówùú sí ara rẹ, o sì ń pa ẹran tí ó wù ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò tọ́jú agbo ẹran.

4. Ìwọ kò ì tíì mú aláìlágbára lára le tàbí wo aláìsàn sàn tàbí di ọgbẹ́ fún ẹni tí o fi ara pa. Ìwọ kò í tíì mú aṣàko padà tàbí wá ẹni tí ó nù. Ìwọ ṣe àkóso wọn ní ọ̀nà lílé pẹ̀lú ìwà òǹrorò.

5. Nítorí náà wọn fọ́n káàkiri nítorí àìsí olùsọ́ àgùntàn, nígbà tí wọ́n fọ́n ká tán wọn di ìjẹ fún gbogbo ẹranko búburú.

6. Àgùntàn mi n rin ìrìn àrè kiri ní gbogbo àwọn òkè gíga àti òkè kékeré. A fọ́n wọn ká gbogbo orí ilẹ̀ ẹni kankan kò sì wá wọn.

7. “ ‘Nítorí náà, ìwọ olùṣọ́ àgùntàn, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa:

8. Níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, nitorí pé agbo ẹran mi kò ní olùṣọ́ àgùntàn nítorí tí a kọ̀ wọ́n, tì wọ́n sì di ìjẹ fún ẹranko búburú gbogbo àti pé, nítorí tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn mi kò ṣe awárí agbo ẹran mi, ṣùgbọ́n wọn ń ṣe ìtọ́jú ara wọn dípò ìtọ́jú agbo ẹran mi,

9. nítorí náà, ẹyin olùsọ́ àgùntàn, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa:

10. Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi ṣe ìlòdì sí àwọn olùsọ́ àgùntàn, èmi yóò sì bèèrè agbo ẹran mi lọ́wọ́ wọn. Èmi yóò sì mú wọn dẹ́kun àti máa darí agbo ẹran mi, tí àwọn olùsọ́ àgùntàn náà kò sì ní lè bọ́ ara wọn mọ́. Èmi yóò gba agbo ẹran mi kúrò ni ẹnu wọn, kì yóò sì jẹ́ oúnjẹ fún wọn mọ́.

11. “ ‘Nítorí èyí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi fúnra mi yóò wá àgùntàn mi kiri, èmi yóò sì ṣe àwárí wọn.

12. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe fojú tó agbo ẹran rẹ̀ tí ó fọ́n ká nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò se fojú tó àgùntàn mi. Èmi yóò gbá wọn kúrò ni gbogbo ibi tí wọ́n fọ́n ká sí ni ọjọ ìkúukùu àti òkùnkùn.

13. Èmi yóò mú wọn jáde kúrò ní àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì kó wọn jọ láti inú àwọn ìlú, èmi yóò sì mú wọn wá sí ilẹ ara wọn. Èmi yóò mú wọn jẹ ni orí àwọn òkè gíga Ísírẹ́lì, ni àárin àwọn òkè àti ní gbogbo ibùdó ilẹ̀ náà.

14. Èmi yóò ṣe ìtọ́jú wọn ní pápá oko tútù dáradára, àní orí àwọn òkè gíga ti Ísírẹ́lì ni yóò jẹ́ ilẹ̀ ìjẹ koríko wọ́n. Níbẹ̀ wọn yóò dùbúlẹ̀ ní ilẹ ìjẹ koríko dídára, níbẹ̀ wọn yóò jẹun ní pápá oko tútù tí ó dara ní orí òkè ti Ísírẹ́lì.

15. Èmi fúnra mi yóò darí àgùntàn mi, èmi yóò mú wọn dùbúlẹ̀, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

16. Èmi yóò ṣe àwárí àwọn tí ó nú, èmi yóò mú àwọn tí ó ń rin ìrìn àrè kiri padà. Èmi yóò di ọgbẹ́ àwọn tí ó farapa, èmi yóò sì fún àwọn aláìlágbára ni okun, ṣùgbọ́n àwọn tí ó sanra tí ó sì ni agbára ní èmi yóò parun. Èmi yóò ṣe olùsọ́ àwọn agbo ẹran náà pẹ̀lú òdodo.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 34