Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 26:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ kìn-ín-ní, oṣù kọ́kànlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

2. “Ọmọ ènìyàn, nítorí pé Tírè sọ nípa Jérúsálẹ́mù pé, ‘Áà! A fọ́ èyí tí í ṣe bodè àwọn orílẹ̀-èdè, a yí i padà sí mi, èmi yóò di kíkún, òun yóò sì di ahoro,’

3. nítorí náà, báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: Kíyèsí i, èmí dojú kọ ọ́ ìwọ Tírè, Èmi yóò sì jẹ́ kí orílẹ̀ èdè púpọ̀ dide sí ọ, gẹ́gẹ́ bí òkun tíi ru sókè.

4. Wọn yóò wó odi Tírè lulẹ̀, wọn yóò sì wo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀; Èmi yóò sì ha ẹrùpẹ̀ rẹ̀ kúrò, Èmi yóò sì sọ ọ́ di orí àpáta.

5. Yóò sì jẹ́ ibi nína àwọ̀n tí wọn fi ń pẹja sí láàárin òkun, ní Olúwa Ọlọ́run wí. Yóò di ìkógun fún àwọn orílẹ̀ èdè.

6. Ìlú tí ó tẹ̀dó sí, ní àárin gbùngbùn ilẹ̀ rẹ̀ ni a ó fi idà sọ ọ́ di ahoro. Nígbà náà ní wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 26