Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 25:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

2. Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí àwọn ará Ámónì kí ó sì sọ àṣọtẹ́lẹ̀ sí wọn.

3. Sì wí fún àwọn ará Ámónì pé, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run tí ó wí pé: Nítorí tí ìwọ wí pé, “Á hà!” Sí ibi mímọ́ mi nígbà tí ó di àìlọ́wọ̀ àti sí orí ilẹ̀ Ísírẹ́lì nígbà tí ó di ahoro; àti sí ilẹ̀ Júdà, nígbà tí wọ́n lọ sí ìgbèkùn,

4. kíyèsí i, nítorí náà ni èmi yóò fi fi ọ lé àwọn ènìyàn ìlà oòrùn lọ́wọ́ ni ohun ìní. Wọn yóò sì gbé ààfin wọn kalẹ̀ nínú rẹ, wọn yóò sì gbé ibùgbé wọn nínú rẹ: wọn yóò jẹ èso rẹ, wọn yóò sì mu wàrà rẹ.

5. Èmi yóò sì sọ Rábà di ibùjẹ, fún àwọn ìbákasíẹ àti àwọn ọmọ Ámónì di ibùsùn fún agbo ẹran. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.

6. Nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Nítorí pé ìwọ pàtẹ́wọ́, ìwọ sì jan ẹsẹ̀ mọ́lẹ̀, tí ìwọ ń yọ̀ pẹ̀lú gbogbo àrankàn rẹ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì

7. nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mi lé ọ, èmi yóò sì fi ọ fún àwọn aláìkọlà fún ìkógun. Èmi yóò sì gé ọ kúrò láàrin àwọn ènìyàn, èmi yóò sì jẹ́ kí o parun kúrò ni ilẹ̀ gbogbo. Èmi yóò sì pa ọ́ run, ìwọ yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 25