Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 24:17-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Má ṣe sunkún, má ṣe gbààwẹ̀ fún òkú. Wé ọ̀já sí orí rẹ, sì bọ bàtà sí ẹsẹ̀ rẹ: má ṣe bo ètè ìsàlẹ̀ rẹ, ma ṣe jẹ oúnjẹ tí àwọn tí ń sọ̀fọ̀ ń jẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà.”

18. Báyìí ni mo sọ̀rọ̀ fún àwọn ènìyàn ní òwúrọ̀, ní àṣálẹ́ ìyàwó mi sì kú. Ní òwúrọ́ ọjọ́ kejì, mo ṣe bí a ti pàsẹ fún mi.

19. Lẹ́yìn náà àwọn ènìyàn bi mí léèrè pé, “Ṣe o kò ni sọ fún wa ohun ti nǹkan wọ̀nyí ní láti ṣe pẹ̀lú wa?”

20. Mo sọ báyìí fún wọn pé, “Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 24