Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 23:6-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Aṣọ aláró ni a fi wọ̀ wọ́n, àwọn gómìnà àti àwọn balógun, gbogbo wọn jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà àwọn tí ń gun ẹsin.

7. O fi ara rẹ̀ fún gbajúmọ̀ ọkùnrin Ásíríà gẹ́gẹ́ bí pansága obìnrin, o fi òrìsà gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́,

8. kò fi ìwa aṣẹ́wó tí ó ti bẹ̀rẹ̀, ni Éjíbítì sílẹ̀, ní ìgbà èwe rẹ̀ àwọn ọkùnrin n bá a sùn, wọn fi ọwọ́ pa àyà èwe rẹ̀ lára wọn sì ń ṣe ìfẹ́kúùfẹ́ sí i.

9. “Nítorí náà mo fi i sílẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, ará Ásíríà, tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i.

10. Wọ́n bọ́ ọ sí ìhòòhò, wọ́n sì gba àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọn sì pá wọn pẹ̀lú idà. Ó di ẹni ìfisọ̀rọ̀ sọ láàrin àwọn obìnrin wọ́n sì fi ìyà jẹ ẹ́.

11. “Àbúrò rẹ̀ Óhólíbà rí èyí, síbẹ̀ nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti aṣẹ́wó rẹ̀, Ó ba ara rẹ jẹ́ ju ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ.

12. Oun náà ní ìfẹ́kúùfẹ́ sí ará Ásíríà àwọn gómìnà àti àwọn balógun, jagunjagun nínú aṣọ ogun, àwọn tí ń gun ẹṣin, gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà.

13. Mo rí i pé òun náà ba ara rẹ̀ jẹ́; àwọn méjèèjì rìn ojú ọ̀nà kan náà.

14. “Ṣùgbọ́n ó tẹ̀ ṣíwájú nínú ṣíṣe aṣẹ́wó. O ri àwòrán àwọn ọkùnrin lára ògiri, àwòrán àwọn ara Kálídíà àwòrán púpa,

15. pẹ̀lú ìgbànú ni ìdí wọn àti àwọn ìgbàrí ni orí wọn; gbogbo wọn dàbí olórí kẹ̀kẹ́ ogun Bábílónì ọmọ ìlú Kálídíà.

16. Ní kété tí ó rí wọn, ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí wọn, ó sì rán onísẹ́ sí wọn ni Kálídíà.

17. Àwọn ará Bábílónì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, lórí ìbùsùn ìfẹ́, nínú ìfẹ́kúùfẹ́ wọn, wọ́n bà á jẹ́. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n bà á jẹ́ tán, ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn ní ìtìjú.

18. Nígbà tí ó tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ̀ ní gbangba wọ́n sì túu sí ìhòòhò, mo yí padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ìtìjú, gẹ́gẹ́ bí mo ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

19. Síbẹ̀síbẹ̀ ó ń pọ̀ síi nínú ìdàpọ̀ rẹ̀ bí ó ti ń rántí ìgbà èwe rẹ̀ tí ó jẹ́ asẹ́wó ní Éjíbítì.

20. Níbẹ̀ ni ó ti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, tí àwọn tí ǹnkan ọkùnrin wọn dàbí ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ẹni tí ìtíjáde ara wọn dàbí ti àwọn ẹṣin.

21. Ó ń fojúsọ́nà sí àìlófin ìgbà èwe rẹ̀ ni Éjíbítì, nìgbà tí wọ́n fi ọwọ́ pa igbáàyà rẹ̀ àti ọmú ìgbà èwe rẹ̀.

22. “Nítorí náà, Óhólíbà, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò gbé olólùfẹ́ rẹ dìde sí ọ, àwọn tí o kẹ́yìn si ní ìtìjú, èmi yóò sì mú wọn dojú kọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà

23. àwọn ará Bábílónì àti gbogbo ara Kálídíà àwọn ọkùnrin Pékódùk àti Ṣóà àti Kóà àti gbogbo ará Ásíríà pẹ̀lú wọn, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà, gbogbo àwọn gómìnà àti balógun, olórí oníkẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn onípò gíga, gbogbo àwọn tí ń gun ẹṣin.

24. Wọn yóò wa dojú kọ ọ pẹ̀lú ohun ìjà, kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ẹrù àti pẹ̀lú ìwọ́jọpọ̀ ènìyàn; wọn yóò mú ìdúró wọn lòdì sí ọ ní gbogbo ọ̀nà pẹ̀lú àṣà ńlá àti kékeré pẹ̀lú àsíborí. Èmi yóò yí ọ padà sí wọn fun ìjìyà, wọn yóò sì fi ìyà jẹ ọ gẹ́gẹ́ bí wọn tí tó.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 23