Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 23:3-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Wọn ń ṣe panṣágà ní Éjíbítì, wọn ń ṣe panṣaga láti ìgbà èwe wọn. Ní ilẹ̀ yẹn ni wọn ti fi ọwọ́ pa ọyàn wọn, níbẹ̀ ni wọn sì fọwọ́ pa igbá àyà èwe wọn.

4. Èyí ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Óhólà, àbúrò rẹ̀ sì ń jẹ́ Óhólíbà. Tèmí ni wọn, wọ́n sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Óhólà ni Samaríà, Óhólíbà sì ni Jérúsálẹ́mù.

5. “Óhólà ń ṣe asẹ́wó nígbà tí ó sì jẹ́ tèmi; Ó sì ṣe ìfẹ́kúfẹ́ sí àwọn olólùfẹ̀ rẹ̀, àwọn jagunjagun ará Ásíríà.

6. Aṣọ aláró ni a fi wọ̀ wọ́n, àwọn gómìnà àti àwọn balógun, gbogbo wọn jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà àwọn tí ń gun ẹsin.

7. O fi ara rẹ̀ fún gbajúmọ̀ ọkùnrin Ásíríà gẹ́gẹ́ bí pansága obìnrin, o fi òrìsà gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́,

8. kò fi ìwa aṣẹ́wó tí ó ti bẹ̀rẹ̀, ni Éjíbítì sílẹ̀, ní ìgbà èwe rẹ̀ àwọn ọkùnrin n bá a sùn, wọn fi ọwọ́ pa àyà èwe rẹ̀ lára wọn sì ń ṣe ìfẹ́kúùfẹ́ sí i.

9. “Nítorí náà mo fi i sílẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, ará Ásíríà, tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i.

10. Wọ́n bọ́ ọ sí ìhòòhò, wọ́n sì gba àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọn sì pá wọn pẹ̀lú idà. Ó di ẹni ìfisọ̀rọ̀ sọ láàrin àwọn obìnrin wọ́n sì fi ìyà jẹ ẹ́.

11. “Àbúrò rẹ̀ Óhólíbà rí èyí, síbẹ̀ nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti aṣẹ́wó rẹ̀, Ó ba ara rẹ jẹ́ ju ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ.

12. Oun náà ní ìfẹ́kúùfẹ́ sí ará Ásíríà àwọn gómìnà àti àwọn balógun, jagunjagun nínú aṣọ ogun, àwọn tí ń gun ẹṣin, gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà.

13. Mo rí i pé òun náà ba ara rẹ̀ jẹ́; àwọn méjèèjì rìn ojú ọ̀nà kan náà.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 23