Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 23:19-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Síbẹ̀síbẹ̀ ó ń pọ̀ síi nínú ìdàpọ̀ rẹ̀ bí ó ti ń rántí ìgbà èwe rẹ̀ tí ó jẹ́ asẹ́wó ní Éjíbítì.

20. Níbẹ̀ ni ó ti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, tí àwọn tí ǹnkan ọkùnrin wọn dàbí ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ẹni tí ìtíjáde ara wọn dàbí ti àwọn ẹṣin.

21. Ó ń fojúsọ́nà sí àìlófin ìgbà èwe rẹ̀ ni Éjíbítì, nìgbà tí wọ́n fi ọwọ́ pa igbáàyà rẹ̀ àti ọmú ìgbà èwe rẹ̀.

22. “Nítorí náà, Óhólíbà, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò gbé olólùfẹ́ rẹ dìde sí ọ, àwọn tí o kẹ́yìn si ní ìtìjú, èmi yóò sì mú wọn dojú kọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà

23. àwọn ará Bábílónì àti gbogbo ara Kálídíà àwọn ọkùnrin Pékódùk àti Ṣóà àti Kóà àti gbogbo ará Ásíríà pẹ̀lú wọn, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà, gbogbo àwọn gómìnà àti balógun, olórí oníkẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn onípò gíga, gbogbo àwọn tí ń gun ẹṣin.

24. Wọn yóò wa dojú kọ ọ pẹ̀lú ohun ìjà, kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ẹrù àti pẹ̀lú ìwọ́jọpọ̀ ènìyàn; wọn yóò mú ìdúró wọn lòdì sí ọ ní gbogbo ọ̀nà pẹ̀lú àṣà ńlá àti kékeré pẹ̀lú àsíborí. Èmi yóò yí ọ padà sí wọn fun ìjìyà, wọn yóò sì fi ìyà jẹ ọ gẹ́gẹ́ bí wọn tí tó.

25. Èmi yóò sì dojú ìbínú owú mi kọ ọ́, wọn yóò sì fìyà jẹ ọ́ ní ìrunnú. Wọ́n yóò gé àwọn imú àti àwọn ètí yín kúrò, àwọn tí ó kù nínú yín yóò ti ipá idà ṣubú. Wọn yóò mú àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin yín lọ, àwọn tí o kù nínú yín ni iná yóò jó run.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 23