Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 23:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

2. “Ọmọ ènìyàn, obìnrin méjì wà, ọmọ ìyá kan náà.

3. Wọn ń ṣe panṣágà ní Éjíbítì, wọn ń ṣe panṣaga láti ìgbà èwe wọn. Ní ilẹ̀ yẹn ni wọn ti fi ọwọ́ pa ọyàn wọn, níbẹ̀ ni wọn sì fọwọ́ pa igbá àyà èwe wọn.

4. Èyí ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Óhólà, àbúrò rẹ̀ sì ń jẹ́ Óhólíbà. Tèmí ni wọn, wọ́n sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Óhólà ni Samaríà, Óhólíbà sì ni Jérúsálẹ́mù.

5. “Óhólà ń ṣe asẹ́wó nígbà tí ó sì jẹ́ tèmi; Ó sì ṣe ìfẹ́kúfẹ́ sí àwọn olólùfẹ̀ rẹ̀, àwọn jagunjagun ará Ásíríà.

6. Aṣọ aláró ni a fi wọ̀ wọ́n, àwọn gómìnà àti àwọn balógun, gbogbo wọn jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà àwọn tí ń gun ẹsin.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 23