Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 22:9-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nínú rẹ ni àwọn ayanijẹ ènìyàn pinnu láti tàjẹ̀ sílẹ̀; nínú rẹ ní àwọn tí ó ń jẹun ní orí òkè ojúbọ òrìṣà, wọn sì hùwà ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́.

10. Nínú rẹ ní àwọn ti kò bu ọla fún àwọn àkéte baba wọn; nínú rẹ ni àwọn ti o ń bá àwọn obìnrin lò nígbà tí wọ́n ń ṣe àkókò lọ́wọ́, ní àsìkò tí a ka wọn sì aláìmọ́.

11. Nínú rẹ ọkùnrin kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ìríra pẹ̀lú aya aládùúgbò rẹ̀, òmíràn bá ìyàwó ọmọ rẹ̀ ṣe, òmíràn sì bá arábìnrin rẹ̀ lòpọ̀ èyí tí í ṣe ọbàkan rẹ̀.

12. Nínú rẹ àwọn ènìyàn gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀; Ìwọ gba èlé lọ́pọ̀pọpọ̀ láti mú aláìsòótọ́ jèrè láti ara aládùúgbò rẹ nípa ìrẹ́jẹ. Ìwọ sì ti gbàgbé ẹ̀ mi; ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

13. “ ‘Èmi yóò kúkú pàtẹ́wọ́ lórí èrè àìmọ̀ tí ìwọ ti jẹ, àti lórí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀ ní àárin yín.

14. Ǹjẹ́ ìwọ yóò lè ní ìgboyà tó, tàbí ọwọ́ rẹ yóò ni agbára ní ọjọ́ tí èmi yóò ni ṣíṣe pẹ̀lú rẹ? Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀, Èmi yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀.

15. Èmi yóò tú kán ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò fọ́n ọ ká sí àwọn ìlú; èmi yóò sì fi òpin sí àìmọ́ rẹ.

16. Nígbà tí a ó bà ọ́ jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀ èdè, ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 22