Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 21:6-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. “Nítorí náà, mí ìmí ẹ̀dùn ìwọ ọmọ ènìyàn! Mi ìmí ẹ̀dùn pẹ̀lú ọkàn ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn kíkorò ní iwájú wọn.

7. Bí wọ́n bá sì bi ọ́, wí pé, ‘Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń mi ìmí ẹ̀dùn?’ Ìwọ yóò wí pé, ‘Nítorí ìròyìn tí ó ń bẹ. Gbogbo ọkàn ni yóò yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yóò sì di aláìlera; gbogbo ọkàn ní yóò dákú, gbogbo eékún ni yóò sì di aláìlera bí omi?’ Ó ń bọ̀! Yóò sì wa sí ìmúṣẹ dandan, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”

8. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

9. “Ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀ wí pé, Èyí yìí ní Olúwa wí:“ ‘Ìdá kan, Ìdá kan,tí a pọ́n tí a sì kùn

10. a ti pọ́n fún pípa,a sì dan an kí ó lè máa kọ bí mọ̀nàmọ́ná!“ ‘Àwa yóò ha si ọ̀pá aládé ọmọ mi Júdà? Idà kẹ́gàn gbogbo ọ̀pá.

11. “ ‘Idà ní a yàn láti pọ́n,kí ó lè ṣe é gbá mú;a pọ́n ọn a sì dan án,ó ṣetán fún ọwọ́ àwọn apani.

12. Sunkún síta, kí ó sì pohùnréré ẹ̀kún, ọmọ ènìyàn,nítorí yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi;yóò wá sórí gbogbo ọmọ aládé Ísírẹ́lììbẹ̀rù ńlá yóò wá sórí àwọn ènìyàn minítorí idà náà;nítorí náà lu oókan àyà rẹ.

13. “ ‘Ìdánwò yóò dé dandan. Tí ọ̀pá aládé Júdà èyí tí idà kẹ́gàn, kò bá tẹ ṣíwájú mọ́ ńkọ́? Ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.’

14. “Nítorí náà, ọmọ ènìyàn,sọ tẹ́lẹ̀ kí ó sì fí ọwọ́ lu ọwọ́Jẹ́ kí idà lu ara wọn lẹ́ẹ̀méjì,kódà ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta.Ó jẹ́ idà fún ìpànìyànidà fún ìpànìyàn lọ́pọ̀lọpọ̀Tí yóò sé wọn mọ́ níhìnín àti lọ́hùnnún.

15. Kí ọkàn kí ó lè yọ́kí àwọn tí ó ṣubú le pọ̀,mo ti gbé idà sí gbogbo bodè fún ìparunÁà! A mú kí ó kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná,a gbá a mú fún ìparun.

16. Ìwọ idà, jà sí ọ̀túnkí o sì jà sí òsìlọ ibikíbi tí ẹnu rẹ bá dojúkọ

17. Èmi gan an yóò pàtẹ́wọ́ìbínú mi yóò sì rẹlẹ̀Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀.”

18. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mi wá:

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 21