Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 21:22-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Nínú ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ìbò Jérúsálẹ́mù yóò ti wá, ní ibi tí yóò ti gbé afárá kalẹ̀, láti pàṣẹ fún àwọn apànìyàn, láti mú ki wọn hó ìhó ogun láti gbé òòlù dí ẹnu ọ̀nà ibodè, láti mọ odi, àti láti kọ́ ilé ìṣọ́.

23. Yóò dàbí àmì èké sí àwọn tí ó ti búra ìtẹríba fún un, ṣùgbọ́n òun yóò ran wọn létí ẹbí wọn yóò sì mú wọn lọ sí ìgbèkùn.

24. “Nítorí náà èyíí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Nítorí ti ẹ̀yin ti mú ẹ̀bi yín wá sí ìrántí nípa ìṣọ̀tẹ̀ ní gbangba, ní ṣíṣe àfihàn àwọn ẹ̀sẹ̀ rẹ nínú gbogbo ohun tí ó ṣe, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí, a yóò mú yín ní ìgbékùn.

25. “ ‘Ìwọ aláìmọ́ àti ẹni búburú ọmọ aládé Ísírẹ́lì, ẹni ti ọjọ́ rẹ̀ ti dé, ẹni tí àsìkò ìjìyà rẹ̀ ti dé góngó,

26. Èyí yìí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Tú ìwérí kúrò kí o sì gbé adé kúrò. Kò ní rí bí ti tẹ́lẹ̀: Ẹni ìgbéga ni a yóò sì rẹ̀ sílẹ̀,

27. Ìparun! Ìparun! Èmi yóò sé e ni ìparun! Kì yóò padà bọ̀ sípò bí kò se pé tí ó bá wá sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ni in; òun ni èmi yóò fifún.’

28. “Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn sọ̀tẹ̀lẹ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí nípa àwọn ará Ámónì àti àbùkù wọn:“ ‘Idà kan idà kantí á fa yọ fún ìpànìyàntí a dán láti fi ènìyàn ṣòfòàti láti kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná!

29. Bí ó tilẹ jẹ́ pé a rì èké nípa yínàti àfọ̀sẹ èké nípa yína yóò gbé e lé àwọn ọrùnènìyàn búburú ti a yóò pa,àwọn tí ọjọ́ wọn ti dé,àwọn tí ọjọ́ ìjìyà wọn ti dé góńgó.

30. Dá idà padà sínú akọ rẹ̀Níbi tí a gbé sẹ̀dá yín,ní ibi tí ẹ̀yin ti sẹ̀ wá.

31. Níbẹ̀ ni èmi yóò ti ṣe ìdájọ́ yín,èmi yóò sì fi èémí ìbínú gbígbónámi bá yín jà.

32. Ẹ̀yin yóò jẹ́ èpò fún iná náà,a yóò ta ẹ̀jẹ̀ yin sórí ilẹ̀ yín,a ki yóò rántí yín mọ́;nitorí èmi Olúwa ní ó ti wí bẹ́ẹ̀.’ ”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 21