Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 21:18-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mi wá:

19. “Ọmọ ènìyàn la ọ̀nà méjì fín idà ọba Bábílónì láti gbà, kí méjèèjì bẹ̀rẹ̀ láti ìlú kan náà. Ṣe àmì sí ìkòríta ọ̀nà tí ó lọ sí ìlú náà.

20. La ọ̀nà kan fún idà láti wá kọ lu Rábà ti àwọn ará Ámónì kí òmíràn kọ lu Júdà, kí ó sì kọ lu Jérúsálẹ́mù ìlú olódi.

21. Nítorí ọba Bábílónì yóò dúró ni ìyànà ní ojú ọ̀nà, ní ìkóríta, láti wá àmìn nǹkan tí ń bọ̀: Yóò fi ọfà di ìbò, yóò bèèrè lọ́wọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀, òun yóò ṣe àyẹ̀wò ẹ̀dọ̀.

22. Nínú ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ìbò Jérúsálẹ́mù yóò ti wá, ní ibi tí yóò ti gbé afárá kalẹ̀, láti pàṣẹ fún àwọn apànìyàn, láti mú ki wọn hó ìhó ogun láti gbé òòlù dí ẹnu ọ̀nà ibodè, láti mọ odi, àti láti kọ́ ilé ìṣọ́.

23. Yóò dàbí àmì èké sí àwọn tí ó ti búra ìtẹríba fún un, ṣùgbọ́n òun yóò ran wọn létí ẹbí wọn yóò sì mú wọn lọ sí ìgbèkùn.

24. “Nítorí náà èyíí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Nítorí ti ẹ̀yin ti mú ẹ̀bi yín wá sí ìrántí nípa ìṣọ̀tẹ̀ ní gbangba, ní ṣíṣe àfihàn àwọn ẹ̀sẹ̀ rẹ nínú gbogbo ohun tí ó ṣe, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí, a yóò mú yín ní ìgbékùn.

25. “ ‘Ìwọ aláìmọ́ àti ẹni búburú ọmọ aládé Ísírẹ́lì, ẹni ti ọjọ́ rẹ̀ ti dé, ẹni tí àsìkò ìjìyà rẹ̀ ti dé góngó,

26. Èyí yìí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Tú ìwérí kúrò kí o sì gbé adé kúrò. Kò ní rí bí ti tẹ́lẹ̀: Ẹni ìgbéga ni a yóò sì rẹ̀ sílẹ̀,

27. Ìparun! Ìparun! Èmi yóò sé e ni ìparun! Kì yóò padà bọ̀ sípò bí kò se pé tí ó bá wá sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ni in; òun ni èmi yóò fifún.’

28. “Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn sọ̀tẹ̀lẹ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí nípa àwọn ará Ámónì àti àbùkù wọn:“ ‘Idà kan idà kantí á fa yọ fún ìpànìyàntí a dán láti fi ènìyàn ṣòfòàti láti kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná!

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 21