Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 19:3-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ó sì tọ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà, ó sì di kìnnìún tó ní agbára,ó kọ́ ọ láti sọdẹ, ó sì ń pa àwọn ènìyàn jẹ.

4. Àwọn orílẹ̀ èdè gbọ́ nípa rẹ̀,wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n mú un nínú ààfin wọn.Wọn fi ẹ̀wọ̀n mu nu lọ sí ilẹ̀ Éjíbítì.

5. “ ‘Nígbà tí abo kìnìún yìí rí pé ìrètí rẹ̀ sì já sí asán,ó mú ọmọ rẹ̀ mìíràn ó sì tún tọ́ ọ dàgbà di kìnnìún tó ní agbára.

6. Ó sì ń rìn káàkiri láàrin àwọn kìnnìún nítorí pé ó ti lágbára,o kọ ọdẹ ṣíṣe, ó sì pa àwọn ènìyàn.

7. Ó sì wó odi wọn palẹ̀ ó sì sọ àwọ̀n ìlú wọn di ahoro.Ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé ibẹ̀ sì wà ní ìpayà nítorí bíbú ramúramù rẹ̀.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 19