Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 19:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. “ ‘Ìyá rẹ dàbí àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ̀;tí á gbìn sí etí odò ó, kún fún èso,ó sì kún fún ẹ̀ka nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi,

11. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lágbára tó láti fi ṣe ọ̀pá àṣẹ ìjòyè,ó ga sókè láàrin ewé rẹ̀,gíga rẹ̀ hàn jáde láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka rẹ̀.

12. Ṣùgbọ́n a hú àjàrà yìí pẹ̀lú ìbínú,á sì wo o lulẹ̀, afẹ́fẹ́ láti ìlà oorùn sì mú koko,wọ́n sọ ọ́ di aláìléso,àwọn ẹka rẹ̀ tó lágbára tẹ́lẹ̀ sì rọ wọ́n sì jó wọn.

13. Báyìí, a tún ún gbìn sínú aṣálẹ̀ ni ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tó ń pọ̀ǹgbẹ omi.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 19