Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 17:9-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. “Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí nìyí: Yóò wá gbilẹ̀ bí? A kò wá ní i wú gbòǹgbò rẹ̀, ki a si gé èso rẹ̀ kúrò kí ó bá à le rọ? Gbogbo ewé rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ni yóò rẹ̀. Kò sì ní gba agbára tàbí ènìyàn púpọ̀ láti fà gbòngbò rẹ̀ tu.

10. Bí a tilẹ̀ tún un gbìn, yóò wa gbilẹ̀ bí? Kò wá ní i rọ pátapáta nígbà ti afẹ́fẹ́ láti ìlà oòrùn bá kọ lù ú. Gbogbo ewé rẹ̀ yóò rẹ̀ lórí ilẹ̀ tó ti dàgbà?’ ”

11. Nígbà náà, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mi wá pé:

12. “Sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé yìí, ‘Ǹjẹ́ ẹ mọ ìtumọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?’ Sọ fún wọn: ‘Ọba a Bábílónì wá sí Jérúsálẹ́mù ó sì kó Ọba àti àwọn ìjòyè ọmọ aládé ibẹ̀ lọ sí Bábílónì lọ́dọ̀ rẹ̀.

13. Lẹ́yìn èyí ó bá ọ̀kan nínú ọmọ Ọba dá májẹ̀mú, ó mú un jẹ́ ẹ̀jẹ́ ìbúra ó tún kó àwọn ìjòyè ilẹ̀ náà.

14. Kí ìjọba ilẹ náà le re lẹ̀, láì ní le gbérí mọ́, àyàfi tí ó bá pa májẹ̀mú rẹ mọ ni yóò tó ó lè dúró.

15. Ṣùgbọ́n Ọba ṣọ̀tẹ̀ sí i nípa ríran aṣojú lọ sí Éjíbítì, kí wọn bá à lè fún-un ni ẹsin àti àwọn ọmọ ogun púpọ̀. Yóò ha ṣe àṣeyorí? Ṣe ẹni tó ṣe irú nǹkan yìí yóò sì bọ́ níbẹ̀? Yóò wá da májẹ̀mú kó sì bọ́ níbẹ̀ bí?

16. “ ‘Bí mo ti wà láàyè ni Olúwa Ọlọ́run wí, níbi tí Ọba tó fi sórí oyè wà, ẹ̀jẹ́ ẹni tí ó kẹ́gàn àti májẹ̀mú ẹni tí ó dà, níbẹ̀ ni àárin Bábílónì ní yóò kùú sí.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 17