Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 17:5-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. “ ‘Ó mú lára irúgbìn ilẹ̀ náà, ó gbìn ín sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi, ó gbìn ín bí igi wílóò.

6. Ó dàgbà, ó sì di àjàrà to kúrú ṣùgbọ́n to bolẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kọjú si i, gbòǹgbò rẹ̀ sì dúró lábẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni o di àjàrà ó sì mu ẹ̀ka àti ewe jáde.

7. “ ‘Ṣùgbọ́n ẹyẹ Idì ńlá mìíràn tún wá, tó ní apá títóbi pẹ̀lú ìyẹ́ púpọ̀. Gbòǹgbò àjàrà náà sì ta lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti orí ilẹ̀ tí wọn gbìn ín sí, ó wá pẹ̀ka lọ sọ́dọ̀ rẹ kí ó le fún-un ni omi.

8. Orí ilẹ̀ tó dára lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi ni a gbìn ín sí, kí ó bá à le pẹ̀ka, kò sí so èso, ó sì wá di igi àjàrà tó lọ́lá púpọ̀.’

9. “Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí nìyí: Yóò wá gbilẹ̀ bí? A kò wá ní i wú gbòǹgbò rẹ̀, ki a si gé èso rẹ̀ kúrò kí ó bá à le rọ? Gbogbo ewé rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ni yóò rẹ̀. Kò sì ní gba agbára tàbí ènìyàn púpọ̀ láti fà gbòngbò rẹ̀ tu.

10. Bí a tilẹ̀ tún un gbìn, yóò wa gbilẹ̀ bí? Kò wá ní i rọ pátapáta nígbà ti afẹ́fẹ́ láti ìlà oòrùn bá kọ lù ú. Gbogbo ewé rẹ̀ yóò rẹ̀ lórí ilẹ̀ tó ti dàgbà?’ ”

11. Nígbà náà, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mi wá pé:

12. “Sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé yìí, ‘Ǹjẹ́ ẹ mọ ìtumọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?’ Sọ fún wọn: ‘Ọba a Bábílónì wá sí Jérúsálẹ́mù ó sì kó Ọba àti àwọn ìjòyè ọmọ aládé ibẹ̀ lọ sí Bábílónì lọ́dọ̀ rẹ̀.

13. Lẹ́yìn èyí ó bá ọ̀kan nínú ọmọ Ọba dá májẹ̀mú, ó mú un jẹ́ ẹ̀jẹ́ ìbúra ó tún kó àwọn ìjòyè ilẹ̀ náà.

14. Kí ìjọba ilẹ náà le re lẹ̀, láì ní le gbérí mọ́, àyàfi tí ó bá pa májẹ̀mú rẹ mọ ni yóò tó ó lè dúró.

15. Ṣùgbọ́n Ọba ṣọ̀tẹ̀ sí i nípa ríran aṣojú lọ sí Éjíbítì, kí wọn bá à lè fún-un ni ẹsin àti àwọn ọmọ ogun púpọ̀. Yóò ha ṣe àṣeyorí? Ṣe ẹni tó ṣe irú nǹkan yìí yóò sì bọ́ níbẹ̀? Yóò wá da májẹ̀mú kó sì bọ́ níbẹ̀ bí?

16. “ ‘Bí mo ti wà láàyè ni Olúwa Ọlọ́run wí, níbi tí Ọba tó fi sórí oyè wà, ẹ̀jẹ́ ẹni tí ó kẹ́gàn àti májẹ̀mú ẹni tí ó dà, níbẹ̀ ni àárin Bábílónì ní yóò kùú sí.

17. Nígbà tí wọ́n bá pa bùdó ogun tì í, tí wọ́n sì mọ odi láti pa ọ̀pọ̀ ènìyàn, Fáráò pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun àti àjọ ńlá rẹ̀ kò ní lè ṣe ìrànwọ́ fún-un lójú ogun.

18. Nítorí pé ó kẹ́gàn ẹ̀jẹ́ nípa dída májẹ̀mú, àti pé ó juwọ́ sílẹ̀ nínú ṣíṣe ìlérí, kò ní i bọ níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn nǹkan to ṣe yìí.

19. “ ‘Nítorí náà Olúwa Ọlọ́run wí pé: Bí mo ti wà láàyè, Èmi yóò mú ẹ̀san ẹ̀jẹ́ mi tó kẹ́gàn àti májẹ̀mú mi tó dà wa sórí rẹ̀.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 17