Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 17:21-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Gbogbo ìsáǹsá àti ọ̀wọ́ ọmọ ogun rẹ̀ ni yóò kú pẹ̀lú idà, èmi yóò sì fọn àwọn ìyókù ká sínú afẹ́fẹ́ káàkiri. Nígbà náà ni yóò mọ̀ pé, “Èmi Olúwa lo sọ̀rọ̀.”

22. “ ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: Èmi fúnra mi yóò mú ọ̀kan lára ẹ̀ka tí ó ga jùlọ lori igi Kédàrí gíga, tí èmi yóò sì gbìn ín, èmi yóò sì gé ọ̀mùnú tí ó sẹ̀sẹ̀ yọ láti òkè, èmi yóò sì gbìn ín sórí òkè tó ga tó sì lókìkí.

23. Ní ibi gíga òkè Ísírẹ́lì ni èmi yóò gbìn ín sí; yóò pẹ̀ka, yóò sì so èso yóò wa di igi Kédárì tí ó lọ́lá. Orírsìírísìí ẹyẹ yóò sì fi òjìji abẹ ẹ̀ka rẹ ṣe ibùgbé; wọn yóò ṣe ibùgbé si abẹ́ òjìji ẹ̀ka rẹ̀

24. Gbogbo igi inú oko yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa ni ó mú igi gíga walẹ̀, tí mo sì mú kúkurú ga sókè, tí mo mu igi tútù gbẹ, tí mo sì mú igi gbígbẹ rúwé.“ ‘Èmi Olúwa ni ó sọ bẹ́ẹ̀, Èmi yóò sì se e.’ ”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 17