Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 16:5-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Kò sẹ́ni tó ṣàánú tàbí kẹ́dùn rẹ débi àtiṣe ikankan nínú iwọ́nyi fún ọ ṣùgbọ́n lọ́jọ́ ìbí rẹ, ìta la jù ọ́ sí torí wọ́n kórìíra rẹ.

6. “ ‘Nígbà tí mo sì kọjá tí mo rí ọ tó ń jàgùdù nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ, mo sọ fún ọ pé, “Yè!”

7. Mo mú ọ dàgbà bí ohun ọ̀gbìn inú oko. O ga sókè, o sì dàgbà, o wá di arẹwà jùlọ, ọmú rẹ yọ, irun rẹ gùn, ìwọ tí o wà ní ìhòòhò láì fi nǹkan kan bora.

8. “ ‘Nígbà tí mo tún kọjá, tí mo rí ọ, mo rí i pé àsìkò àti nífẹ́ rẹ ti tó, mo fi iṣẹtí aṣọ mi bo ìhòòhò rẹ. Mo jẹ́jẹ̀ẹ́ fún ọ mo sì bá ọ dá májẹ̀mú láti di tèmi, ni Olúwa Ọlọ́run wí,

9. “ ‘Nígbà náà ni mo fi omi wẹ ẹ̀jẹ̀ kúrò lára rẹ, mo fi ìpara pa ọ́ lára.

10. Mo fi aṣọ oníṣẹ́ ọ̀nà sí ọ lára láti wọ̀ ọ́, mo wọ bàtà aláwọ fún ọ. Mo fi aṣọ funfun lẹlẹ àti aṣọ olówó iyebíye ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́.

11. Mo fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, mo fi ẹ̀gbà ọwọ́ sí ọ lọ́wọ́, mo fi ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn sí ọ lọ́rùn,

12. Mo sì tún fi òrùka sí ọ nímú, mo fi yẹtí sí ọ létí, mo sì fi adé tó rẹwà dé ọ lórí.

13. Báyìí ni mo ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú wúrà àti fàdákà; tí aṣọ rẹ jẹ́ funfun lẹlẹ, olówó iyebíye àti aṣọ tí a ṣiṣẹ́ ọnà sí. Ìyẹ̀fun kíkúnná, oyin àti òróró ni oúnjẹ rẹ. O di arẹwà títí o fi dé ipò ayaba.

14. Òkìkí rẹ sì kàn káàkiri orílẹ̀ èdè nítorí ẹwà rẹ, nítorí dídán tí mo fi ṣe ẹwà rẹ láṣe pé, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

15. “ ‘Ṣùgbọ́n, o gbẹ́kẹ̀lé ẹwà rẹ, o sì di alágbérè nítorí òkìkí rẹ. O sì fọ́n oju rere rẹ káàkiri sórí ẹni yòówù tó ń kọjá lọ, ẹwà rẹ sì di tìrẹ.

16. O mú lára àwọn aṣọ rẹ, láti rán aṣọ aláràbarà fún ibi giga òrìṣà tí o ti ń ṣàgbèrè. Èyí kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, tàbí kó tilẹ̀ ṣẹlẹ̀ rárá.

17. O tún mú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ dáradára tí mo fi wúrà àti fàdákà ṣe fún ọ láti fi yá ère ọkùnrin tí ó ń bá ọ ṣe àgbèrè papọ̀.

18. O sì wọ ẹ̀wù oníṣẹ́ ọnà rẹ fún wọn, o sì tún gbé òróró àti tùràrí mi sílẹ̀ níwájú wọn.

19. O tún gbé oúnjẹ tí mo fún ọ-ìyẹ̀fún dáradára, òróró àti oyin-fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn; ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyìí, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

20. “ ‘Àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin tí o bí fún mi lo ti fi rúbọ bí oúnjẹ fún àwọn òrìṣà. Ṣé ìwà àgbèrè rẹ kò ha tó bí?

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 16