Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 16:26-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. O ṣe àgbèrè pẹ̀lú ará Éjíbítì tí í ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ aládúgbò rẹ láti mú mi bínú pẹ̀lú ìwà àgbèrè rẹ tó ń pọ̀ sí i.

27. Nítorí náà ni mo fi na ọwọ mi lòdì sí ọ, mo ge ilé rẹ kúrú; èmi yóò sì mú ìfẹ́ àwọn to korìíra rẹ ṣẹ́ lé ọ lórí, àwọn ọmọbìnrin Fílístínì ti ìwàkiwà rẹ̀ jẹ ìyàlẹ́nu fún,

28. Nítorí àìnítẹ́lọ́rùn rẹ o ṣàgbérè pẹ̀lú ara Ásíríà; síbẹ̀ náà, o kò tún ní ìtẹ́lọ́rùn.

29. Ìwà àgbèrè rẹ tún tẹ̀ṣíwájú dé ilẹ̀ oniṣòwò ni Bábílónì síbẹ̀ náà, o kò tún ni ìtẹ́lọ́rùn.

30. “Olúwa Ọlọ́run wí pé, ‘Báwo ni ọkàn rẹ ṣe jẹ aláìlera tó tí o n ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ àwọn agídí alágbérè!

31. Nígbà tí o kọ́lé funra rẹ, tóo sì tún kọ ojúbọ gíga si gbogbo òpin ojú pópó síbẹ̀, o ko tún ṣe bi àwọn alágbèrè gidi nítorí pé o kọ̀ láti gbowó

32. “ ‘Ìwọ alágbèrè aya! Ìwọ fẹ́ràn ọkùnrin àjèjì ju ọkọ rẹ lọ!

33. Àwọn ọkùnrin máa ń sanwó fún àwọn aṣẹwó ni ṣùgbọ́n ìwọ lo tún ń sanwó fun wọn, tí ó tún ń fún àwọn olólùfẹ́ rẹ lẹ́bùn àti owó ẹ̀yìn kí wọn bá à le máa wá ọ wá láti gbogbo agbègbè fún àgbèrè ṣíṣe.

34. Nínú àgbèrè rẹ ìwọ yàtọ̀ sí àwọn alágbèrè obìnrin yòókù; kò sí ẹni tó ń wá ọ fún àgbèrè. Ìwọ ló ń sánwó: nígbà tí wọn yóò sanwó fún ọ, ìdákejì ni ọ́; nítorí pé ìwọ ló ń sanwo bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò rí gbà.

35. “ ‘Nítorí náà, ìwọ alágbèrè, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa!

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 16