Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 16:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

2. “Ọmọ ènìyàn, mú kí Jérúsálẹ́mù mọ gbogbo ìwà ìríra rẹ̀.

3. Sọ pé, ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí sí Jérúsálẹ́mù: Ìran rẹ àti ilẹ̀ ìbí rẹ wà ní ilẹ̀ Kénáànì; ará Ámórì ni baba rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ará Hítì.

4. Ní ọjọ́ tí a bí ọ, a kò gé okùn ìwọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì fomi wẹ̀ ọ́ láti mú kí o mọ́, tàbí ká fiyọ̀ pa ọ́ lára tàbí ká fi aṣọ wé ọ.

5. Kò sẹ́ni tó ṣàánú tàbí kẹ́dùn rẹ débi àtiṣe ikankan nínú iwọ́nyi fún ọ ṣùgbọ́n lọ́jọ́ ìbí rẹ, ìta la jù ọ́ sí torí wọ́n kórìíra rẹ.

6. “ ‘Nígbà tí mo sì kọjá tí mo rí ọ tó ń jàgùdù nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ, mo sọ fún ọ pé, “Yè!”

7. Mo mú ọ dàgbà bí ohun ọ̀gbìn inú oko. O ga sókè, o sì dàgbà, o wá di arẹwà jùlọ, ọmú rẹ yọ, irun rẹ gùn, ìwọ tí o wà ní ìhòòhò láì fi nǹkan kan bora.

8. “ ‘Nígbà tí mo tún kọjá, tí mo rí ọ, mo rí i pé àsìkò àti nífẹ́ rẹ ti tó, mo fi iṣẹtí aṣọ mi bo ìhòòhò rẹ. Mo jẹ́jẹ̀ẹ́ fún ọ mo sì bá ọ dá májẹ̀mú láti di tèmi, ni Olúwa Ọlọ́run wí,

9. “ ‘Nígbà náà ni mo fi omi wẹ ẹ̀jẹ̀ kúrò lára rẹ, mo fi ìpara pa ọ́ lára.

10. Mo fi aṣọ oníṣẹ́ ọ̀nà sí ọ lára láti wọ̀ ọ́, mo wọ bàtà aláwọ fún ọ. Mo fi aṣọ funfun lẹlẹ àti aṣọ olówó iyebíye ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 16