Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 15:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé:

2. “Ọmọ ènìyàn, báwo ni igi àjàrà ṣe dára ju igi mìíràn lọ tàbí jù ẹ̀ka àjàrà tó wà láàrin igi yòókù nínú igbó?

3. Ǹjẹ́ a wa lè mú igi lára rẹ̀ ṣe nǹkan ti o wúlò bí? Tàbí kí ènìyàn fi ṣe èèkàn tí yóò fi nǹkan kọ́?

4. Lẹ́yìn èyí, ṣe a jù ú sínú iná gẹ́gẹ́ bí epo ìdáná, gbogbo igun rẹ̀ jóná pẹ̀lú àárin rẹ, ṣé o wà le wúlò fún nǹkan kan mọ́?

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 15