Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 12:6-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Gbé ẹrù rẹ lé èjìká lójú wọn, bo ojú rẹ, kí o má ba à rí ilẹ̀, sì ru ẹrù rẹ lọ lálẹ́ nítorí pé mo fi ọ́ ṣe àmì fún ilé Ísírẹ́lì.”

7. Mo ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún mi. Mo kẹ́rù mi jáde lọ́sàn án láti lọ fun ìgbèkùn. Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, mo dá ògiri lu pẹ̀lú ọwọ́ mi. Mo sì gbẹ́rù mi léjìká nínú òkùnkùn lójú wọn.

8. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

9. “Ọmọ ènìyàn, Ǹjẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ilé Ísírẹ́lì tilẹ̀ bi ọ́ pé, ‘Kí lohun tó ń ṣe túmọ̀ sí?’

10. “Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí kan àwọn ọmọ aládé Jérúsálẹ́mù àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì tó wà láàrin rẹ.

11. Sọ fún wọn, Mo jẹ́ àmì fún yín’.“Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe, bẹ́ẹ̀ la ó ṣe sí wọn. Wọn ó kó lọ sí ìgbèkùn. Gẹ́gẹ́ bí ẹni ti a dè ní ìgbèkùn

12. “Ọmọ aládé tó wà láàrin wọn yóò di ẹrù rẹ lé èjìká lálẹ́ yóò sì jáde lọ, òun náà yóò da ògiri lu kí ó le gba ibẹ̀ jáde. Yóò sì bo ojú rẹ̀ kí ó má ba à rí ilẹ̀.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 12