Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 12:10-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. “Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí kan àwọn ọmọ aládé Jérúsálẹ́mù àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì tó wà láàrin rẹ.

11. Sọ fún wọn, Mo jẹ́ àmì fún yín’.“Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe, bẹ́ẹ̀ la ó ṣe sí wọn. Wọn ó kó lọ sí ìgbèkùn. Gẹ́gẹ́ bí ẹni ti a dè ní ìgbèkùn

12. “Ọmọ aládé tó wà láàrin wọn yóò di ẹrù rẹ lé èjìká lálẹ́ yóò sì jáde lọ, òun náà yóò da ògiri lu kí ó le gba ibẹ̀ jáde. Yóò sì bo ojú rẹ̀ kí ó má ba à rí ilẹ̀.

13. N ó ta àwọ̀n mi lé e lórí, yóò sì kó sínú okùn, N ó sì mú lọ sí Bábílónì, ní ilẹ̀ Kádíyà, ṣùgbọ́n kò ní fojú rí ilẹ̀ náà ibẹ̀ ni yóò kú sí.

14. Gbogbo àwọn tó yí i ká láti ràn án lọ́wọ́ (opá ìtẹ̀lẹ̀ àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀) ni N ó túká sí afẹ́fẹ́, n ó sì tún fi idà lé wọn kiri.

15. “Wọn ó sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, tí mo bá tú wọn ká láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, tí mo sì fọ́n wọn ká sí ilẹ̀ káàkiri.

16. Ṣùgbọ́n n ó ṣẹ́ díẹ̀ kù lára wọn, lọ́wọ́ idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn, kí wọn le jẹ́wọ́ gbogbo ìṣe ìríra wọn láàrin àwọn orílẹ̀ èdè yìí. Nígbà náà ni wọn ó mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 12