Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 8:5-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ọmọ-mààlu rẹ ti ta ọ́ nù ìwọ Ṣamáríà! Ju ère tí o gbẹ́ nùÌbínú mi ń ru sí wọn:yóò ti pẹ́ tó kí wọ́n tó dé ipò àìmọ̀kan?

6. Ísírẹ́lì ni wọ́n ti wá!Ère yìí—agbẹ́gilére ló ṣe éÀní ère Samáríà, ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́.

7. “Wọ́n gbin afẹ́fẹ́wọ́n sì ká ìjìIgi ọkà kò lórí,kò sì ní mú oúnjẹ wá.Bí ó bá tilẹ̀ ní ọkààwọn àlejò ni yóò jẹ.

8. A ti gbé Ísírẹ́lì mì,Báyìí, ó sì ti wà láàrin àwọn orílẹ̀ èdèbí ohun èlò tí kò wúlò.

9. Nítorí pé wọ́n ti gòkè lọ sí Síríàgẹ́gẹ́ bí ẹhànnà kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó ń rìn kiri.Éfúráímù ti ta ara rẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀.

10. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn sí àárin orílẹ̀ èdèÈmi ó ṣà wọ́n jọ nísinsìn yìíWọn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòfò dànùlọ́wọ́ ìnílára ọba alágbára.

Ka pipe ipin Hósíà 8